Màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla (MOA) jáde láti bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, (I.Y.P) sọ̀rọ̀ ní ọjọ́’rú tí ó jẹ́ ọjọ́ kẹrin oṣù Ọ̀pẹ, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìn lé lógún, lóri àwọn èdèàiyedè tó nlọ ní orílẹ̀ èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba D.R.Y, tí ó fa ìjì, èyí tí ó sì da ìpòruru sí ọkàn àwọn I.Y.P.

Gẹ́gẹ́bí olórí rere tí Ọlọ́run jo’gún ọpọlọ àti làákàyè fún lọ́pọ̀lọ́pọ̀, màmá wa MOA dá ti ọ̀tún fún ọ̀tún, wọ́n sì dà ti òsì fún òsì láí ṣe ègbè lẹ́yìn ẹnikẹ́ni.

Màmá wa MOA tú àṣírí pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tí wọ́n npè ara wọn ní ọba nílẹ̀ Yorùbá ni, pẹ̀lú àwọn olóṣèlú aríremáṣe nàìjíríà tí wọ́n nfipá jẹ gàba ní orílẹ̀ èdè wa, àwọn ẹni wọ̀nyi nwá ọ̀nà láti ṣe ìdènà fún àwọn Adelé wá, kí wọ́n má lè wọlé sí oríkò ile iṣẹ́ ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa.

Nítorínáà ní àwọn ẹni ibi yí ṣe nsa iṣẹ́ burúkú láti fi èèdì mú àwọn tó nṣiṣẹ́ pẹ̀lú MOA kí ohun gbogbo lè dojúrú. Màmá MOA sọ gbangba pé Ọlọ́run ló nṣe iṣẹ́ D.R.Y, nítorí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè ja wá’lẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú ẹ̀, onítọ̀hún á parun lójijì.

Ìyá òmìnira àwa ọmọ Aládé tún tẹ́síwájú láti fí ọkàn àwọn tó nbọkànjẹ́ balẹ̀ pé, kò sí ìbẹ̀rù kankan fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, nítorí orílẹ̀ èdè D.R.Y ti dúró, ìjì kò  sìlè bì í wó lulẹ̀, ó sì dájú pé àwọn Adelé wa yíó wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa láì pẹ́ yìí nítorí a ma ṣí àwọn ajẹgàba nàìjíríà ní ìdí kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí màmá wa MOA bá àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P sọ fi ìtura sí wa ní ọkàn, o sì pa 

gbogbo ìjì lẹ́nu mọ́ pátápátá. Ọjọ́ ayẹyẹ wa ti wọlé tán.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.