Kàkà kí n bí ẹgbàá ọ̀bùn, ma kúkú bí ọ̀kan ṣoṣo ọ̀gá.
Ọ̀rọ̀ yí dá lórí ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ níbi tí a ti rí ọ̀rẹ́ méjì kan tí wọ́n ń fi ènìyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwọn ṣe oògùn owó, tí wọ́n sì tún ń ta ẹ̀yà ara ènìyàn pẹ̀lú.
Orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ méjì náà ni Ayodeji Saheed àti Tunde Obadimeji. Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ nínú ìròyìn náà, wọ́n wípé àwọ́n ti pa ó lé ní àádọ́rin ọ̀dọ́bìnrin níye.
Nítòótọ́, ohun tí àwọn ọmọkùnrin yí ṣe kò dára rárá, ohun tó burú púpọ̀ ni, ṣùgbọ́n tí a bá b’ẹ́ran wí, ó yẹ kí a b’ẹ́ràn náà wí, ṣebí ohun tí àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà sọ àwọ́n ọ̀dọ́ wa dà ni, ọ̀dọ́ tó jáde ilé ìwé tí kò rí iṣẹ́ fún bíi àìmọye ọdún, tí kò sì ní ìrètí pé ọjọ́ báyìí ni yóò dára fún òun, nígbà wo ni kò ní ronú láti wá ọ̀nà àbáyọ fún ara rẹ̀, nígbàtí ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kò dájú.
Ẹ wo iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti rán lọ sọ́run àrèmabọ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ burúkú yí, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹnìkíní títí tó fi d’órí àádọ́rin ènìyàn, ẹnikẹ́ni kò sì rí wọn láti ìgbà náà, wọ́n sì ní àwọn ní ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún iṣẹ́ búburú naa, haa, ó ga ò!
Ṣé iṣẹ́ ibi kan náà ló kúkú wà lọ́wọ́ àwọn agbófinró ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria pàápàá, kódà àwọn gan-an ni ó tún máa ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún àwọn òníṣẹ́ ibi, báwo ní ètò ààbò tó péye ṣe fẹ́ wà fún àwọn ará ìlú nígbàtí àwọn agbófinró bá ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún àwọn arúfin?
Ara ìdí nì yí tí màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fi dìde, wípé ó tó gẹ́ẹ́, ìran àwọn kò tún jìyà mọ́, ṣùgbọ́n ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà ṣì ń tẹ̀síwájú láti f’agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, wọ́n kọ̀ láti fi àyè sílẹ̀ fún àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá láti máa jẹ ìgbádùn ìjọba wa pẹ̀lú ìlànà tí Olódùmarè ti fi fún wa nípasẹ̀ màmá wa.
Àwa ọmọ Yorùbá tún ń rán ẹ̀yìn agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà létí o, àwa kìí ṣe ará Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlelogun ní a ti gba omìnira wa, a sì ti búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọ́kọrẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, a wá ń fi dáa yín lójú ní àkókò yí pé, yálà ẹ fẹ́ o tàbí ẹ kọ̀, ẹ máa kúrò lórí ilẹ wa láì pẹ́ yìí, nítorí pé orí àga tí ẹ jókòó lé yẹn kìí ṣe àyè yín, ti àwa ọmọ Yorùbá ni, ẹ kò ní ẹ̀tọ́ láti wà níbẹ̀ rárá.
Ẹ kó ìwà ìpànìyàn àti ìjẹgàba yín lọ sí Nàìjíríà yín, nítorí a ti ṣetán láti ṣí yín nìdìí ní àìpẹ́ yìí, kí àwọn ọ̀dọ́ wa náà lè rí ògo wọn lò, ìran Yorùbá kìí se apànìyàn.
Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ní sùúrù, àkókò díẹ̀ lókù, ẹ má jẹ̀ẹ́ kí a máa wá owó ní ọ̀nà tí kò tọ́, ìwà tí kò bójú mu ni eléyìí jẹ, nítorí pé ìsèjọba Orílẹ̀ Èdè D.R.Y kò ní gba ìwà ibi láàyè rárá.