Ní agbára Olódùmarè, ní kété tí àwọn Alákòóso wa bá ti wọlé sí ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa ni ìyàtọ̀ ńlá yóò bẹ̀rẹ̀ nínú ìgbé ayé gbogbo àwa ọmọ Aládé. Kò ní sí àyè fún ẹnìkan láti ma kàwọ́ sókè fẹsẹẹ̀ jan’lẹ̀, níwájú ẹnikẹ́ni bí ẹru mọ́, nítorí ògo oníkálukú á bẹ̀rẹ̀ síi búyọ, kò ní sí ìdí láti máa wojú ẹnikẹ́ni kí a tó ṣe ohunkóhun ní rere.
Gégébí àlàyé tí màmá wa òrìṣà òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe, àlàkalẹ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), kún fún àwọn ètò tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fun gbogbo ọmọ Yorùbá láti lo ẹ̀bùn àti ọgbọ́n àtinúdá tí Olódùmarè fún wọn kí wọ́n lè ṣe rere nínú ayé.
Irin iṣẹ́ tí àwọn olóṣèlú, àwọn gbajúmọ̀, àwọn tí wọ́n pe ara wọn lọ́ba àti àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ wọn ń lò láti kó ará ìlú lẹ́rú, pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́, ni àìsí ilé ẹ̀kọ́ tó yè kooro, àìsí iṣẹ́, òṣì, títẹ ẹ̀tọ́ ẹni lójú mọ́lẹ̀ láti fi agbára tẹrí ẹni ba àti àìní ìrètí. Wọ́n tún pèsè òògùn olóró fún awon ọ̀dọ́ láti sọ wọ́n di ìdàkudà, arúfin, apaniyan, agbowó ipá ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ́ lọ, kí wọ́n lè tẹ̀síwájú nínú ìsìnrú fún àwọn ìkà, àgbà ìyà, àti àwọn ọmọ wọn.
Gbogbo àwọn àṣírí yí ni Ọlọ́run fi han Ìyá wa MOA pẹ̀lú ọ̀nà àbáyọ tí ó ti wà nínú àlàkalẹ ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́. Lára ọ̀nà àbáyọ náà ni, ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó yè kooro láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkàwé gboyé àkọ́kọ́ ní fásitì, inú ilé ìwé àti ọgbà ilé ìwé tó dára pẹ̀lú ààbò tó dájú, ìpèsè iṣẹ́ tó dára, iná mọ̀nàmọ́ná, ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé fún IYP láti ṣe òwò láì san àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ènìyàn kò sì nílò láti mọ baba ìsàlẹ̀ kankan.
Màmá wa ti jẹ́ ka mọ̀ pé àparò kan kò ní ga jù kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Ẹni tó bá ya ọ̀lẹ nìkan ni kòní rọ́wọ́ mú, nítorí náà ọmọ Aládé kò ní ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni.