Èmi àti àwọn tó wà ní ipò ìsèjọba pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá ni a jọ máa ń lọ sí ibùdó àwọn agbésùnmọ̀mí láti lọ dúnnàá-dúrà, Gumi ló sọ gbólóhùn yí nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́. 

Ó wípé, kò sí ìgbà tí òun lọ sí ibùdó àwọn agbésùnmọ̀mí yí láì sí àwọn ìjọba àti àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú òun nítorí pé, ibẹ̀ kò ṣeé lọ láìsí àtìlẹ́yìn àwọn ọlọ́pàá, wọn kàn máa fún òun ní gbèdéke ibi tí wọ́n gbọ́dọ̀ de ni. Nígbà míràn ẹ̀wẹ̀, àwọn ọba ní wọn máa ń tẹ̀lé òun lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá. Wọn yóò ṣí ilẹ̀kùn fún wa, aò sì jókòó láti jíròrò. 

Ó tẹ̀síwájú wípé, ìjọba kò leè ká’pá àwọn agbésùnmọ̀mí yí pẹ̀lú àwọn ọmọ ológun rárá, ọ̀rọ̀ náà kàn dàbí lílo oògùn orí fífọ́ fún ibà lásán ni,nítorí pé,ọ̀dọ́ ni púpọ̀ nínú àwọn agbésùnmọ̀mí yí,ohun tó leè yanjú ọ̀rọ̀ náà ni ìjókòó pẹ̀lú ìjọba fún ìjíròrò, kìí ṣe nípa kíkó àwọn ọmọ ológun lọ síbẹ̀, àti pé ìjọba kàn ń fi owó ṣòfò ni bí ó ṣe ń rà ohun èlò ìjagun,nítorí kò leè sí àṣeyọrí kankan. 

Gbogbo wa náà ni a mọ̀ wípé, ìjọba aríremáse nàìjíríà fúnra rẹ̀ gan-an ni agbésùnmọ̀mí, àwọn ni á pe olè wá jà, àwọn náà ni á pe olóko kó wá múu. 

Àwa ìran Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó gbà wá lọ́wọ́ àwọn apaná ògo yí. Kò sí èyí tó kàn wá pẹ̀lú aríremáse nàìjíríà. Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ni tiwa,kò rújú rárá.