Nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti gbọ́ nípa ìpàdé tí àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì nípa ìlera ènìyàn tí àwọn Àjọ fún Ètò Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣe láìpẹ́ yí, kókó ohun tí ìpàdé wọn dá lé lórí ni, àrùn kan tí wọ́n ń pe orúkọ rẹ̀ ní Monkey pox tí wọ́n ní ó sì ti pọ̀ ní Ilẹ̀ Áfríkà, wọ́n sì tí ń gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè abẹ́rẹ́-àjẹsára báyìí láti kojú àìsàn náà.
Wọn se àlàyé àwọn ìpènijà tí wọ́n ń kojú ní àwọn orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan èyí tí ó mú kí àbẹ́rẹ́-àjẹsára náà má tíì fi dé àwọn orílẹ̀ èdè náà.
Nínú ìpàdé náà wọ́n dárúkọ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti ní àkọsílẹ̀ ààrùn yìí àti iye àwọn tí ó ti níi. Wọ́n wá dárúkọ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi ìlú àkọ́kọ́ tí ó ti ṣetán tí ó sì ti gbà ìfọwọ́sí ìlànà láti gba abẹ́rẹ́-àjẹsára ọ̀hún, bíótilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ń dárúkọ àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ti ní àkọsílẹ̀ ààrùn yìí, wọn kò mẹ́nu ba Nàìjíríà rárá.
Ọ̀rọ̀ yí ìbá má ti kàn wá tí ó bá jẹ́ pé àwọn gómìnà agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n ń fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ti kúrò ní, nítorí kò sí ohun tí ó kàn wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Nàìjíríà yálà wọ́n gba abẹ́rẹ́-àjẹsára o tàbí wọn kò gbàá, kò kan àwa ọmọ Yorùbá.
Ṣùgbọ́n a fẹ́ fi àkókò yí sọ fún àwa ènìyàn wa wípé, ẹ jẹ́ kí a kíyèsára gidigidi, kí a má báwọn gba abẹ́rẹ́-àjẹsára kankan o, irọ́ pátápátá gbáà ni ó wà nídìí ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́-àjẹsára tí wọ́n ń kó káàkiri wọ̀nyí, ọ̀nà láti ṣe ìjàǹbá fún wa ni.
Ẹnití ó ńpè ẹ́ kò tíì sinmi, o wá ní ò ń gbọ́ àgbọ̀ya, àwọn aláwọ̀ funfun wọ̀nyí kò sinmi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì dákẹ́, lójoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ oríṣiríṣi láti dín iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù, pàápàá jùlọ, àwa aláwọ̀ dúdú, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra.
Tí a bá tilẹ̀ ni àìsàn tàbí ààrùn kankan, abẹ́rẹ́-àjẹsára èyí tí àwọn WHO nsọ yí, kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ tí ènìyàn fi leè gbógun ti àìsàn náà.
Ṣèbí ọ̀nà kan ṣáà ni àwọn babańlá wa ń gbà ṣe ìtọ́jú ara wọn kí àwọn amúnisìn yí tó dé, ṣùgbọ́n nítorí wípé a ti gbàgbọ́ pé ohunkóhun tí ó bá ti jẹ́ ti àwọn aláwọ̀ funfun ni ó dára, ìdí nìyí tí a ò fi náání ohun tí ó jẹ́ tiwa.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó rán ìránṣẹ́ rẹ̀, màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla sí wa ní àkókò yí láti tún ayé ìran Yorùbá ṣe, ṣé ẹ ò gbàgbé pé màmá wa ti sọ fún wa pé, a ó máa lo èwe àti egbò, láti ṣe ìtọ́jú ní àwọn ilé ìwòsàn wa náà.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a f’ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ìgbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ètò lọ́kan-ò- jọ̀kan tí Olódùmarè ti gbé lé màmá wa lọ́wọ́ fún àwa Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.