Àwọn ọmọ adúláwọ̀ tó lọ ṣe àtìpó ní Isreali ni ìjọba ìlú náà ti npè láti darapọ̀ mọ́ ọmọ-oogun wọn, tí wọ́n á sì fún wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ tí kò pé’ye; bí àpẹrẹ, ọ̀sẹ̀ méjì, tí wọ́n á sì kó wọn lọ sógun, pẹ̀lú ìlérí àti fún wọn ní ìwé-ìgbélu.
Irú oore wo nìpá nṣe fẹ́pọ̀n. Kìló kan alàwọ̀-dúdú pẹ̀lú ogun ní Gaza? Àwọn aláwọ̀-ẹlẹ́dẹ̀ ṣá fẹ́ pa ìran adúláwọ̀ run.
Ní òtítọ́ àti ní òdodo, àwọn aláwọ̀ funfun yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èròngbà wọn kò le wá sí ìmúṣẹ, torí a ò ní gbà, síbẹ̀, wọ́n ń tan aláwọ̀dúdú jẹ, wọ́n sì nṣiṣẹ́ tọ̀ọ́ ní ojoojúmọ́!
Ẹ̀bi wọn náà dẹ̀ kọ́ọ; ṣébí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú ní Áfríkà, ni kò bìkítà fún àwọn ọmọ ìlú wọn. Ṣe ni wọ́n ń tari àwọn èèyàn wọn sí’nú ẹrú-ṣíṣe, látàrí pé wọ́n ń ni wọ́n l’ara, tí àwọn yẹn sì ńsálọ lọ sí ìlú àwọn amúnisìn láti lọ ṣe àtìpó.
Nígbà kan rí, ìjọba ìlú Ukraine ké pe àjọ ìgbìmọ̀ adúláwọ̀ wípé kí àwọn ọmọ ìlú wọn darapọ̀ mọ àwọn ọmọ ogun Ukraine láti dojú ìjà kọ ìlú Russia.
Pàápàá jùlọ, ìlú aríremáṣe Nàìjíríà tí ilẹ̀ Yorùbá ti jáde kúrò nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n tó ńfipá jẹ gàba lórí ìlẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).Gbogbo èròńgbà àwọn òyìnbó yìí ni láti pa ìran adúláwọ̀ run.
Nígbàtí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pè fún irú nkan báyí, Màmá wa ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá sọ pé kí Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) má darapọ̀ mọ́ wọn.
A ò gbọ́dọ̀ ti oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn.
Ọpẹ́ ni kí á máa dá báyi lọ́wọ́ Olódùmarè, fún Ìyá wa, Ìyá Ìran Yorùbá, fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n sì ńṣe fún ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
Nítorí ògo Democratic Republic of the Yorùbá, ìrètí wà pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìlú aláwọ̀dúdú yíò kọ́ ẹ̀kọ́ lára ìṣèjọba D.R.Y.