Ó jẹ́ ohun tí ó burú lọ́pọ̀lọpọ̀ pé a rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Yorùbá tí kò mọ̀ pé Aládé ni wọn, tí wọ́n gbàgbé pé ènìyàn ọ̀tọ̀ àti ẹyin lójú Olódùmarè ni wọ́n jẹ̀.
Bẹ́ẹ̀, àwọn àgbà bọ wọ́n ní ọmọ tí o sọ’lé nù, so àpò ìyà kọ́.
Èyí ló dífá fún àwọn ará ìlú Ìsàpà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìsàpà ní Old Ọ̀yọ́ Empire ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) tí àwọn ọlọ́ṣà ajẹgàba nàìjíríà n pè ní Ìpínlè Kwara nítorí wọ́n ṣì ń fi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa.
Àwọn ara Ìsàpà ń pàrọwà sí ìjọba agbésúnmọ̀mí nàíjíria pé kó wá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó nfi ọjọ́ mẹ́ta-mẹ́ta jí àwọn ènìyan mẹ́wàá-mẹ́wàá gbé bí ẹni lọ mú adìyẹ nínú àgò.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wípé, àwọn ará agbègbè yìí ń pe ìjọba aríremáṣe nàìjíríà láti gbà wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n sì wá ǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà.
Kò sí ohun tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà leè ṣe, nítorí òun fúnra rẹ̀ ọ̀gá àwọn agbésùnmọ̀mí ni. Fún ìdí èyí, ẹ má ròpé ohun rere kan tún leè ti ìlú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà jáde mọ́.
Ìdí nìyí tí gbogbo àwa ọmọ Aládé nílé lóko fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé Olùgbàlà dìde fún ìran ọmọ Aládé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí, Ìyá wa, Olóyè Ìyá àfin Modúpẹ́ Onítìrí-Abíọ́lá ni Olódumárè lò láti gba ilẹ̀ wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ́wá ọdún-ó-lé méjìlélógún tí a sì tí bẹ́rẹ́ ìjọba wa ní kété ti a búra wọlé fún Olórí Adelé wa bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ni ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún .
Láì pẹ́ yìí tí a bá ti lé àwọn ọ̀tá ohun rere, agbesunmomi nàìjíríà ọ̀dájú tó nfi agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa kúrò, àwọn ìjọba Adelé wa yóò wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní gbogbo ìpínlẹ̀ wa, ìjínigbé yóò sì di ohun ìgbàgbé, bẹ́ẹ̀ ni ààbò tó dájú yóò wà fún ẹ̀mí àti dúkìá.
ìgbáradì àjọyọ̀ ni ó ku fún gbogbo ọmọ Aládé ní kété tí ipè bá dún, àwa ọmọ Yorùbá ti ṣoríire!