Ọmọ Yorùbá, etí yín mélo o? Ẹ ṣọ́’ra! Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kan l’ó sọ bẹ́ẹ̀ o.
Ọ̀rọ̀ yí wá l’erèdí bí àwọn ọmọ Íbò ṣe ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu lọ sí ìlú Èkó, l’erèdí wípé ilẹ̀ àwọn Íbò kò rọgbọ báyi o, nítorí ti àwọn agbé’bọn àìmọ̀ (unknown gunmen) àti bí wọ́n ṣe nsọ fún àwọn ọmọ Íbò ní ìlú wọn wípé kí wọ́n máa fi tipátipá gbé’lé (sit-at-home).
Ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn ọmọ Íbò ni a gbọ́ wípé wọ́n nsọ wípé, kàkà tí àwọn kò fi ní lè lọ sí’bi òwò àwọn ní ilẹ̀ Íbò tìtorí ti k’onílé-gbé’lé (sit-at-home), àwọn á kúkú kúrò ní ilẹ̀ Íbò, àwọn á sì wá ibi míran gbà lọ.
A gbọ́ wípé eléyi ti’lẹ̀ wọ́’pọ̀ l’aárin àwọn Íbò ní ìlú Enugu; tani kò sì mọ̀ wípé tí ọmọ Íbò bá ti nkúrò ní ìlú rẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ wípé ilẹ̀ Yorùbá, pàápàá ìlú Èkó ni wọ́n á kọ́kọ́ ro’nú rẹ̀ l’ati máa bọ̀.
Àwọn kan ti’lẹ̀ nsọ báyi wípé nṣe ni àwọn ọmọ Íbò kan nfi ọ̀rọ̀ unknown gunmen wọn wọ̀nyí, pàápàá, wípé wọ́n nlòó l’ati fi ọgbọ́n lé àwọn ọmọ Íbò kúrò ní ìlú wọn, kí wọ́n le da’rí kọ Ilẹ̀ Yorùbá, pàápàá ìlú Èkó.
Ṣé o pẹ́ tí a ti’lẹ̀ ti mọ̀ wípé t’a bá fi lé ìrònú ọmọ Íbò ni, nṣe ni ó wùú kí Yorùbá pàápàá kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá kí àwọn Íbò wá kúkú gba gbogbo ilẹ̀ Yorùbá kan; à b’ẹ ò rí nkan!
Nṣe ni a kò ti’lẹ̀ wá mọ̀, nínú Fúlàní àti àwọn Ìgbò, èwo gan-an gan ni kì í ṣe ọ̀tá ọmọ Yorùbá nínú wọn?! Fúlàní fẹ́ gba ilẹ̀ Yorùbá fún màlúù wọn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Íbò ndókùkùlajà wípé àwọn ni àwọn lè ṣe ohunk’ohun tí ó bá wu àwọn ní ilẹ̀ Yorùbá.
A ti’lẹ̀ gbọ́ wípé àwọn Íbò ọ̀un sọ wípé tí àwọn bá ti gba gbogbo Èkó tán, nṣe ni àwọn tún máa gba gbogbo ilẹ̀ Yorùbá náà, pàápàá, pẹ̀lú rẹ̀! Hábà!
À b’ẹẹ̀ wá rí? Àti Íbò àti Fúlàní, ọ̀tá Yorùbá ni wọ́n! Ọmọ Yorùbá, tí ẹ bá sùn pa’ra, kò ní dára rárá o! Ẹ má ṣe rò wípé ẹnìkan ni ọ̀rẹ́ yín o! Ojú l’alákàn fi nṣọ́rí ni ọ̀rọ̀ ọmọ Yorùbá wá já sí báyi.
Ẹ jọ̀wọ́, ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá, ẹ má ṣe da ìran yín o! Ẹ má rò wípé ẹnìkan ni ẹ ní l’ọrẹ́, yálà Íbò tàbí Fúlàní, tí kò lè ṣe ìran Yorùbá ní’bi! Rárá o!
Related News: Ẹrù ìjọ̀gbọ̀n ni ó nwọ’lé sí Ìlẹ̀ Yorùbá yío, Ẹ ṣọ́’ra |
Àtìgbẹ́kẹ̀lé Íbò, àtìgbẹ́kẹ̀lé Fúlàní, ìkan ò ṣẹ́ ‘kan ni o! Ilẹ̀ Yorùbá yíi l’ọ̀ràn o! Òun ni ojú àti Fúlàní àti Íbò tí ó ràn mọ́ o! Inkan tiwọn ò kì ntó wọn! Àfi ilẹ̀ Yorùbá yí ṣáá l’ojú wọ́n ràn mọ́.
Ọ̀tọ̀ tún ni ti àwọn òyìnbó amunisin! À fi ilẹ̀ Yorùbá yíi náà ni.
Ọmọ Yorùbá tí kò bá gbá’rùkù ti ìjọba Adelé ní àkókò yí, kí á lé ìjọba Nigeria kúrò ní orí ilẹ̀ wa, kí á le b’ojú tó ohun gbogbo tí Olódùmarè fún wa; á jẹ́ wípé ọ̀dàlẹ̀ pátápátá gbáà ni irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, tí a kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irúfẹ́ wọn ó gbèrú ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.