Wọn ò mọ̀ pé Òbìnrin òyìnbó láti ìlú Netherlands yí, nṣe fídíò wọn, ó sì nya fọ́tò wọn, àwọn kàn ri lórí alùpùpù tí ó ngùn lọ sí Ìlú Abuja ni, ní orílẹ̀-èdè wọn, Nàìjíríà; ni àwọn ọlọ́pa Nàìjíríà méjì ọ̀ún wá dáa dúró pé kí ó fún àwọn lówó!
Ibi tí wọ́n ti nrẹ́rin, tí wọ́n nfẹyín kẹkẹkẹ, pé àwọn ti rí nkan jẹ, wọn ò mọ̀ pé gbajúgbajà tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ “Itchy boots” ní ẹ̀rọ ayélujára YouTube ni, ṣùgbọ́n tí orúkọ rẹ̀ gan-gan njẹ́ Noraly, ni obìnrin yí. Iṣẹ́ fíìmù ṣíṣe ni ó yàn láàyò, tí ó sí nífẹ gidi sí kí ó máa gun alùpùpù rẹ̀ káàkiri àgbáyé.
Ṣé irúfẹ́ ẹni tí ó nṣe irú iṣẹ́ yẹn á kúkú ti ní oríṣiríṣi èròjà ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé tó mbẹ lára rẹ̀, tí ẹlòmíràn kò mọ̀, tí ó fi nṣe fídíò tí ó dẹ̀ nya fọ́tò láì gbé nkan ìyafọ́tò ọ̀ún dání – ó ti wà lára rẹ̀!
Nṣe ni àwọn àṣìtáánì tí wọ́n npè ní Ọlọ́pa Nàìjíríà méjì yí ri o, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní tọrọ owó; òun náà mbá wọn rẹ́rin, tí wọn ò mọ̀ pé ó nya fọ́tò wọn, bẹ́ẹ̀ ló nṣe fídíò wọn.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo nkan tó yà ló gbé sórí ẹ̀rọ ayélujára káàkiri àgbáyé! Ni àwọn aláṣẹ ọlọ́pa wọn ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà bá bọ́ aṣọ lọ́rùn àwọn olọ́pa wọn méjì ọ̀ún.
Èwo ti ẹ̀ ni tiwa nínú ọ̀rọ̀ náà gan-an? Tiwa ni pé Èdùmàrè mà ṣe wá lóore, gidi, ṣé bí àwa náà ìbá ṣe gba ojútì káàkiri àgbáyé nìyẹn, tí kìí bá nṣe jíjáde tí a ti jáde kúrò nínú ìlú adójútini wọn ọ̀ún, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a dẹ̀ ti ní ìṣèjọba-ara-ẹni tiwa báyi, láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-ló-gún.
Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), kí a máa gbọ́, kí a tún tungbọ́, ẹnikẹ́ni, ó ṣe Yorùbá ni, kò ṣe Yorùbá ni, tí ó bá hu ìwà Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) yí, kí ó mọ̀ pé tòun ti bá òun.