Ajá Tó Máa Sọnù Kì Í Gbọ́ Fèrè Ọlọ́dẹ

Olóṣèlú Nigeria kan, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, Honorable Sanya Omirin, ni ọ̀daràn kan ti dárúkọ rẹ̀ o, gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó máa nrán àwọn ní iṣẹ́ ibi, tí ó sì fún àwọn ní ọgbọ̀n ìbọn láti ṣe iṣẹ́ ibi náà.

Èyí tí ó pọ̀jù nínú àwọn ìbọn náà ni ọkùnrin olóṣèlú yí fún wọn kí ó tó di àsìkò ìdìbò nigeria ní ọdún 2023.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024

Ọ̀daràn tí ó sọ eléyi jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, tí orúkọ rẹ̀ sì jẹ́ Bọ̀dé Owóẹ̀yẹ, ẹni tí wọ́n máa npe ní ‘Bọ̀dé Itaapa.’

Ọ̀daràn yí sọ wípé ọmọ ẹgbẹ́ okùnkùn kan, bíi ti òun, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Adéfióyè Solomon (ẹni tí wọ́n tún máa npè ní ‘Solo Iwara’) ni Honourable Olóṣèlú yíi máa nrán sí òun àti àwọn ẹgbẹ́ òun.

Ṣebí nínú ìròhìn kan lórí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ wọ̀nyí – kí ó jẹ́ ẹni tí ó sọ wípé òun nṣe ìlú (atún’lú-ṣe), ni ó nkó ìbọn fún àwọn ará ìlú láti máa pa ara wọn! Tí a bá ní a ò fẹ́ irú olóṣèlú nàìjíríà ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, ọ̀rọ̀ gidi ni o, láti ẹnu ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024

Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo eléyi, tani ó bẹ àwọn ọlọ́pa nàìjíríà fún’ra wọn o, láti máa bá wa mú ọ̀daràn ní orí ilẹ̀ Yorùbá? Nítorí ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kéjìlá oṣù kéje ọdún tí a wà yí ni wọ́n mú ọ̀daràn yí – èyí tí ó sì jẹ́ oṣù mẹ́ta gbáko tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti wa lórí àléfà!

Èyí ní ìtumọ̀ o! Ìtumọ̀ rẹ̀ rèé – àwọn ọlọ́pa tó mú àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ni Ọ̀DARÀN o! Nítorí ọlọ́pa Nàìjíríà ni wọ́n! Wọn ò dẹ̀ ní àṣẹ kankan mọ́, ní pàtàkì, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún yí, tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dé orí àlééfà; wọn ò ní àṣẹ kankan mọ́, ní Orí Ilẹ̀ Yorùbá!

Ẹ fi ọmọ Yorùbá sílẹ̀ o! Ẹ̀yin ọlọ́pa nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, àti káàkiri Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. A ò bẹ̀ yín níṣẹ́ kankan o.

Ẹ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, ẹ fi àwọn ọmọ wa sílẹ̀; ẹ kó ara yín kúrò nínú gbogbo bárékè àti ibùdó ọlọ́pa tí ó wà ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, tí ẹ ò bá fẹ́ rọ́ràn! Ẹ fi àwọn ọ̀dọ́ wa sílẹ̀ fún wa!