Èèyàn bí ìgbín ní hè gbín, ẹni bí ahun níí r’áhun he, Láìpẹ́ yìí ní fọ́nrán kan tó ti fi ìgbà kan jà rànhìn-rànhìn lórí ẹ̀rọ ayélujára tún padà jáde o, níbi tí a ti rí ọkàn lára àwọn olóṣèlú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Umar Ganduje tó ti ń gba owó ẹ̀yìn, èyí tí àwọn àgbà ìyà aláìnílàákàyè kan wá wò ó wípé arákùnrin olórí àwọn gbéwiri yí gan-an ni òye tọ̀ sí ní ilẹ̀ Yorùbá.
Ṣé àtẹnujẹ náà ló wà kò gbogbo làákàyè ẹ̀yin ẹ̀bà tí ẹ pe ara yín lọ́ba ilẹ̀ Yorùbá tó báyìí? Àkọ́kọ́, Umar Ganduje kìí se ọmọ Yorùbá, báwo ni òye Yorùbá ṣe wá di ti ọmọ Fúlàní ?
Èkejì ni wípé, ẹ pé òye náà ni Ààrẹ Afìwàjoyè, se ìwà gbígba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yìí náà? Taló wá ba ayé yín jẹ́ tó báyìí ná ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ wọ̀nyí?
Ní ayé àtijọ́ kí àwọn babańlá wa tó leè fi ẹnìkan joyè láàárín ìlú,wọ́n yóò ṣe ìwádìí ẹni náà dáadáa, àti pé, ifá ni yóò mú ẹni tí oyè bá tọ́ sí, ṣùgbọ́n ṣeni ẹ̀yin àgbà aláìnírònú yí dojú gbogbo rẹ̀ bolẹ̀ tí ẹ sì ba orí àpèrè àwọn baba yín jẹ́ nítorí owó àti dúkìá tí ẹ máa padà fi sílẹ̀.
Báwo ni ẹ ò ṣe ní fi olórí àwọn ọlọ́ṣà jẹ òye nígbà tó jẹ́ wípé, irú kan náà ni gbogbo yín. Ẹ ta ìran yín fún Fúlàní, bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ń ba orí ìtẹ́ àwọn babańlá yín jẹ́.
Ṣùgbọ́n a ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó sí’jú àánú Rẹ̀ wò wá, nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, tí kò fi ti àwọn òpònú ọba wọ̀nyí ṣe.
Àwọn tí Olódùmarè fi sí ipò àṣẹ,ṣùgbọ́n torí àtẹnujẹ wọ́n lọ kò ara wọn sábẹ́ olóṣèlú, sebí àwọn Yorùbá sọ wípé, ibi tí a bá pè ní orí, ẹni kan kìí fi í tẹlẹ̀ ? Ó màse o, ọba mìíràn kò leè pàṣẹ ni inú ilé rẹ̀ dé bi yóò pàṣẹ ni ìlú.
Fún ìdí èyí, a tún fẹ́ fi àkókò yí rán an yín létí wípé, kò sí ọba kankan ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá mọ́, kí oníkálukú yín tètè máa ronú ibi tó máa sálọ, nítorí pé a ò tún ní jẹ́ kí ẹ dá wa padà s’óko ẹrú mọ́,gẹ́gẹ́ bí màmá wa ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọmọ Aládé ni gbogbo wa, ẹ má tàn wá jẹ mọ́. Ojú wa ti là!