Ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) tí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nígbàtí ìyá wa, òrìṣà òmìnira Yorùbá, ìyá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) bá wa sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kìíní Oṣù Ṣẹ́rẹ́ ẹgbàá ọdún ó lé márùndínlọ́gbọ̀n nípa ìmúṣẹ ògo àti dídé ọjọ́ àjọyọ̀ wa nínú ọdún yìí.

Bí Olódùmarè tí ló màmá wa rèé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó kọjá pé àwọn Adelé wa yóò wọlé sí ilẹ̀ Yorùbá láti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa, tí ó sì rí bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún pẹ̀lú àtìlẹyìn Ọlọ́run.

Láti ọjọ́ náà tí a ti búra wọlé fún olórí Adelé Aṣàkóso wa, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ni ilẹ̀ Yorùbá tí di orílẹ̀ èdè olómìnira aṣàkóso ara ẹni, lẹ́yìn tí Olódùmarè ti lo ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa MOA láti ṣe ìkéde òmìnira wa kúrò nínú  agbèsùnmọ̀mí nàíjíria ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún, tí ó sì hàn kedere sí gbogbo àgbáyé pé D.R.Y kìí ṣe ara aríremáṣe nàìjíríà mọ́. Síbẹ̀, àwọn apaniṣayọ̀ nàìjíríà kọ̀ láti kúrò lórí ilẹ̀ wa.

Àkójọpọ̀ ètò àwọn òyìnbó amúnisìn tí kìí ṣe ìlú tàbí orílẹ̀-èdè, tí wọ́n ń pè ní nàìjíríà yìí tẹ̀síwájú láti máa jẹ gàba lórí orílẹ̀-èdè wa D.R.Y, wọ́n di agbésùnmọ̀mí, olè, apànìyàn àti ajẹgàba sórí ilẹ̀ wa, tí wọ́n tún ń jí àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì wa kó láì bìkítà fún òfin àgbáyé. 

Màmá wa MOA àti bàbá wa olórí Adelé ti kìlọ̀ fún àwọn ẹni ibi yíì pé kí wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ àti ní oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, ṣùgbọ́n ajá tó bá ma sọnù kò ní gbọ́ fèrè ọlọ́dẹ. 

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù àti ìkìlọ̀ fún àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà pẹ̀lú àwọn olóṣèlú àti ọ̀bàyéjẹ́ tó ń pe ara wọn ní ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, tó ń fọwọ́sowọ́pọ̀, láti kúrò pẹ̀lú apọ́nlé, ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ jálẹ̀, màmá wa, olùfẹ́ ìran ọmọ Aládé tí sọ fún wa pé tí wọ́n bá tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe orí kunkun, ọwọ́ agbára ń bọ̀ láìròtẹ́lẹ̀ láti gbé àwọn ọmọ àlè gómìnà agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tí wọ́n ń fi agídí jẹ gàba lórí orílẹ̀ èdè wa, àti pé ọdún tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ’nú rẹ̀ yí ni, kò sí ní pẹ́ rárá mọ́ tí ọwọ́ agbára yóò gbé wọn, tí àwọn Adelé wa yóò wá wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa láti máa bá iṣẹ́ ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa lọ, kí a lè máa jẹ̀’gbádun àlàkalẹ̀ ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé ọwọ́ màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) fún ìṣe rere àwa ọmọ Aládé 

Gbogbo wa níláti palẹ̀mọ́ de ọjọ́ ológo wa, ní kété tí ìpè àjọyọ̀ náà bá ti dún, kí gbogbo wa fi ijó àti ayọ̀ bọ́ síta láti fi ẹ̀mí ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run Olódùmarè tó rán ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) láti gba ìran Yorùbá kúrò nínú ìparun  àwọn òyìnbó amúnisìn.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal