Àgbà-ìyà Ọbásanjọ́, jóko bí ọmọ̀-ọ̀dọ̀, ẹrú, ní’bi tí àwọn òyìnbó ilé-iṣẹ́ Fan Milk ti ńṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé-iṣẹ́ tuntun láti ṣe wàrà (yógọ́ọ̀tì) ní ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ní ìlú Ìbàdàn, ní ìlòdì sí ìjọba-Adelé D.R.Y, torí Ṣèyí Mákindé tí wọ́n dárúkọ rẹ̀ níbẹ̀ kì nṣe D.R.Y l’ó nṣiṣẹ́ fún!Ìyẹn ìkan; ẹ wá bá wa béèrè lọ́wọ́ àgbà’yà Ọbásanjọ́ pé, ṣé Yógọ́ọ̀tì ni ọpọ́n sún kàn, t’ó njẹ-ẹ́ lógún?

Yàtọ̀ sí pé nṣe ni aríremáse Nàìjíríà ń jẹgàba lórí ilẹ̀ ní tiwọn, tí wọn ò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohunkóhun lórí ilẹ̀ wa, ṣé gbogbo ọgbọ́n orí Ọbásanjọ́, yógọ́ọ̀tì ló kàn? Kò kúkú lè ro’nú fún’ra rẹ̀; ẹrú àwọn òyìnbó yẹn ni! Wọn ò bi dáa kó ní òun ò ní yọjú síbẹ̀! Nǹkan tí wọ́n bá ti sọ fun ló máa ṣe! Abájọ tó fi jóko bí ọmọ-ọ̀dọ̀ pẹ̀lú wọn síbẹ̀.

Àwa ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá, a kú ìfojúsọ́na o, fún ọjọ́ náà tí Ìjọba-Adelé wa máa wọ’lé sínú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa, nígbàtí iṣẹ́ tí wọ́n ti nṣe láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí; ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún á wá hàn kedere, á sì tun máa tẹ̀síwájú.

Tó bá di ìgbà náà, ẹ̀yin Fan Milk á wá sọ tẹnu yín, torí etí yín ò di, pé Yorùbá kò sí lára ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ́! Nǹkan tẹ́-ẹ lọ ṣe pẹ̀lú ajẹgàba Nàìjíríà lórí ilẹ̀ D.R.Y, ẹó wá sọọ́ fún wa nígbà-náà.

Nàìjíríà, palẹ̀ rẹ mọ́! A ti kìlọ̀ fún ọ to!

Democratic Republic of the Yorùbá daily newspaper