Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Báwo ni ẹ ṣe fẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà ní orílè-èdè Nàìjíríà, ìjọba mọ́ mí kí ń mọ̀ ọ́ ni wọ́n ń fi ìjọba Nàìjíríà ṣe, a rí àṣírí èyí nínú ìj’ọ́mọ ènìyàn Justice Kayode Olú Ariwoọlá, kété ti wọn ti búra fún un tán gẹ́gẹ́ bíi adájọ́ àgbà ní orílè-èdè Naijiria ní ọjọ́ kẹta dín-lọ́gbọ́n oṣù kẹfà ẹgbàá ọdún ó-lé-méjì-lé lógún, ohun tí ó kọ́kọ́ ṣe ní wípé ọmọ rẹ̀, Justice Olukayode Ariwoọlá Jnr. ni ó kọ́kọ́ gbé fò sí ipò adájọ́ ilé ẹjọ́ àpapọ̀ ti Federal ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹwàá ẹgbàá ọdún ó-lé-métá-lé-lógún, bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tí ó fo kọjá wọn kúkú gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

 Nínú ọdún kan náà ni o tún fi aburo rẹ Adebayo Lateef Ariwoọlá ṣe ìgbàkejì ọ̀gá adarí ilé ayẹ’wé owó, kò pẹ́ lo tún gbé ìyàwó ọmọ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Ariwoọlá Olúwakèmi Victoria fò fẹrẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́ àpapọ̀ ní Abuja, olú ìlú Nàìjíríà, láti ibẹ̀ lọ máa ṣe iṣẹ́ fún Áàrẹ ti Nàìjíríà.

Kò tún tán sí’bẹ̀ o, ọmọ àbúrò adájọ́ àgbà yí Lateef Adebayo Ganiyu, ní ó fi sí ilé ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn.

Ẹ wá ń pariwo pé àwa IYP ṣe jáde kúrò nínú ìyà tí Nàìjíríà fi ń jẹ wá, nígbàtí àwọn kan ń ṣe bámú bámú la yo, àwa kò mọ̀ pé’bi ń pa ọmọ ẹlòmíràn, ọdún wo ni kí á ṣe ìyẹn dà?, àbí kí a la ojú wa sí’lẹ̀ kí wọ́n fi jẹ wá m’ógún tán, rárá o, kò lè seé’ṣe.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Orílè-èdè tí òfin kankan kò ti s’iṣẹ́ mọ́, ohun gbogbo tí bàjẹ tán, tí kò sì sí ìlọsíwájú mọ́, ẹni tí a kò mọ̀ ri ìbàá kú ní wọn ń fí gbogbo ọ̀rọ̀ ṣe, tí ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀, à fi kí wọ́n máa fi’kú wá ẹni náà kiri ní, ilé ti a fi itọ́ mọ, ìrì ni ó máa wó, èyí pẹ̀lú ìdí tí àwa Indegenous Yorùbá People fi rí làákàyè wa ró, a ti fi ìpìlẹ̀ rere lé’lẹ̀ nípa’sẹ̀ ìṣe tí Modupe Onitiri-Abiola ṣe fún ìran Yorùbá ti ó fi kó wá kúrò lóko ẹrú. Ní Orílẹ̀ èdè wa Democratic Republic of the Yoruba àparò kan ó ní ga ju ìkan lọ