Àwọn òṣìṣẹ́ méjì kan, àwakọ̀ àti olùrànlọ́wọ́-iṣẹ́, ni a gbọ́ pé wọ́n kó àwọn míràn mọ́ra, tí ó jẹ́ pé wọ́n wá ṣekú pa ọ̀gá wọn, Abilékọ Ọlákúnbi Adene, tí ó jẹ́ gbajúmọ̀ olónjẹ ní ìlú Àkúrẹ́, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá wa yí. 

Ọ̀rọ̀ gbogbo lórí alábahun ni ọ̀rọ̀ yí jẹ́ o – kò sí bí a ṣe máa sọọ́ lọ, tí a máa sọọ́ bọ̀, tí gbogbo rẹ̀ ò ní padà wá dá lórí jíjẹgàba tí Nàìjíríà, ìlú agbésùnmọ̀mí, ṣì njẹgàba lórí ilẹ̀ àwa ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), èyíinì, lórí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, tí ó tí jáde kúrò lára Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti gbé ìjọba wa sorí àlééfà láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún; ṣùgbọ́n, títí di wákàtí tí a nkọ ìròhìn yí, tí Nàìjíríà, ìlú agbésùnmọ̀mí ṣì pàpà kọ̀ láti jáde, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè máa bá wa tì wọ́n jáde, kúrò lórí ilẹ̀ wa, láìpẹ́ yí ni o!

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Pẹ̀lú ìtìjú àti ìpayínkeke ni wọ́n dẹ̀ máa jáde – àti Ṣèyí Mákindé, àti Sanwó-Olú, àti Oyèbánjí, àtí Ayédatiwa, àtí Adémọ́lá Adélékè, àti Dàpọ̀ Abíọ́dún, àti Abdulrahman Abdulrazaq, pẹ̀lú èyí tó pera ẹ̀ ní Ododo – àwọn olórí-burúkú dede tí wọ́n fi tipá dúró sórí ìṣèjọba àjèjì, ìṣèjọba-Nàìjíríà tí ó jẹgàba lórí ilẹ̀ àti ènìyàn D.R.Y – kí Olódùmarè tí Ó ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí yín, Ó mú ìṣẹ́gun náà wá sí ojú-ayé àti ojú-ìwòran gbogbo ènìyàn nísiìyí; kí a máṣe rí yín mọ́, tàbí ẹnikẹ́ni mọ́, ní ipò ìjẹgàba lórí ilẹ̀ D.R.Y. Olódùmarè dójú tìyín, ẹ̀yìn Ìkà Ẹ̀dá wọ̀nyí; kí bàbá yín ní Nàìjíríà ó gba ìdájọ́ gbígbóná, kí ó jáwọ́ kúrò lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá.

Èdùmàrè, jọ̀wọ́ bá wa Ṣẹ̀rùbàwọ́n; máṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ wọn kí ó balẹ̀; ṣe ojútì fún wọn bí wọ́n ṣe máà máà sá kúrò lórí àpótí ìjẹgàba wọn ní Ilẹ̀ Yorùbá: jẹ́ kí ìgbóná ó dé bá wọn: kí àìsàn tí ó máa lé wọn àti gbogbo nkan nàìjíríà tí wọ́n gbára lé, ó dé bá wọn ní àkókò yí, kí ilẹ̀ D.R.Y ó bọ́, nísiìyí àti títí láí, kúrò lọ́wọ́ ìjẹgàba wọn.

Ká Ìròyìn Síwájú sí: Ẹ̀JẸ̀ ỌMỌ YORÙBÁ WÀ LỌ́RÙN NÀÌJÍRÍA

Ìbá ṣe pé wọ́n ti kúrò ni, irúfẹ́ ohun tí ó ṣekú pa obìnrin yí ìbá ha ti ṣẹlẹ̀ bí? Olódùmarè, jọ̀wọ́ gba àwọn ènìyàn rẹ, Ìran Yorùbá là, ní àkókò yí; tí a dẹ̀ mọ̀ pé O ti ṣé; A dúpẹ́, Ẹlẹ́da wa. Nàìjíríà ti di ohun ìgbàgbé ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.