Óríṣiríṣi ọ̀nà, báyi, ni Ìjọba àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, Nàìjíríà, nwá báyi o, láti fa ọmọ Yorùbá mọ́’ra, àti láti gbé ojú wọn kúrò ní Orìlẹ̀-Èdè Yorùbá!
Èyí tí ó tún jẹ́ ìròhìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ báyi, wípé, àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba-àpapọ̀ tí ìlú Nigeria (Federal Civil Service – èyíinì, tiwọn l’ọhún) ti gbé fọ́ọ̀mù (èyíinì, ìwé ìkọ̀wé-gba’ṣẹ́) síta o, fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba-àpapọ̀ Nàìjíríà wọn l’ọhún, láti fi fọ́ọ̀mù náà ṣe ìtọ́kasí wípé àwọn fẹ́ ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba-àpapọ̀ wọn l’ọhún!
Ohun tí ó wá jẹ́ ìyàlẹ́nu níbẹ̀ ni wípé, a rí ìwé kan tí ó sọ wípé kí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Ìbàdàn (èyítí àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ṣì npè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́), wípé kí wọ́n máa wá gba fọ́ọ̀mù ọ̀hún láti fi wá iṣẹ́ sí abẹ́ ìjọba-àpapọ̀ Nàìjíríà.
Ọ̀nà méjì ni ìròhìn tí a gbọ́ yí fẹ̀gbẹ́ kan o! Kí oníkálùkù ó dẹ̀ mọ ibi tí ó ti fi ẹ̀gbẹ́ kan òun! L’ọnà kíní, Ṣèyí Mákindé àti ìjọba-agbésùnmọ̀mí Nigeria tí ó fi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa, ilẹ̀ Yorùbá, a ti wá ri báyi o, wípé ìparun ẹ̀yín agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ti dájú; ṣùgbọ́n a ṣì tún máa kì yín nílọ̀ o – tí ojú yín bá fọ́, kí ẹ jẹ́ kí ó là o; tí etí yín bá sì di, kí ẹ jẹ́ kí ó là; èyí tí ẹ npè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yẹn, ilẹ̀ Yorùbá ni o, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y). Ìgbéraga ní nṣíwájú ìparun, ẹ dẹ̀ máa parun!
Láti ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí (2024) ni Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (D.R.Y) ti di Sovereign Nation (Orílẹ̀-Èdè Aṣèjọba-ara-Ẹni), èyí tí ó sì yàtọ̀ pátápátá gbáà sí Nigeria! Bí o kò bá mọ̀, ìwọ Ṣèyí Mákindé, mọ̀ lóni wípé òfin àgbáyé ni o nṣẹ̀ sí o! A ti gbọ́ wípé alágídí ni ẹ́; agídí yẹn dẹ̀ ni ó máa ṣe ìparun fún ẹ!
Ọ̀nà kéjì, èyí tí ọ̀rọ̀ yí pín sí ni wípé, ẹnikẹ́ni ní ọmọ Yorùbá, tí ó bá ti wá’ṣẹ́ lọ sí abẹ́ Nigeria, ní àkókò yí tí ó jẹ́ wípé, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba tirẹ̀, kí ó mọ̀ dájú wípé, òun ti pàdánù ìjẹ́-ọmọ-Yorùbá òun lábẹ́ òfin o! Wípé o jẹ́ ọmọ Yorùbá nínú ẹ̀jẹ̀ kò túmọ̀ sí wípé o jẹ́ ọmọ Yorùbá lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè Yorùbá o!
Òfin orílẹ̀-èdè Yorùbá, ní àkókò yí, kòì tíì sọ bóyá ilẹ̀ Yorùbá fi ara mọ́ gbí-gba ìj’ọmọ-ìlú ní orílẹ̀-èdè méjì lẹ́ẹ̀kan náà tàbí kò faramọ!
Nítorí náà, tí ó bá ti fò fẹ̀rẹ̀ báyi wípé o nlọ wá iṣẹ́ ìjọba lábẹ́ ìjọba Nàìjíríà, nísiìyí tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti ní Ìjọba Tirẹ̀, ó túmọ̀ sí wípé o ti pàdánù jíjẹ́ Ọmọ Yorùbá ní orí ilẹ̀ Yorùbá nìyẹn o, o sì ti fara mọ́ jíjẹ́ ọmọ Nigeria!
Èyí tí a tún ní láti wá mọ̀, dájú, báyi, ọmọ Yorùbá, ni wípé, Nàìjíríà ndọ́gbọ́n láti máa kó àwọn ọmọ Yorùbá kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá, kí ó má bàa sí ẹni tí yíò ṣe iṣẹ́ gbígbé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá dìde nígbà tí a bá ti wọ inú Secretariat tán; ṣùgbọ́n, irọ́ ni wọ́n npa! àwa ni a ní ìṣẹ́gun lórí wọn.