Ọ̀tọ̀ ni kí ènìyàn máa sọ nkan tó wùú; ọ̀tọ̀ ni kí ó sọ ohun tó ti gbọ́ láti inú ẹ̀mí wá.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè, tí ó fún wa ní Adarí, èyíinì, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), Adarí tí ó mọ ohùn Olódùmarè, tí ó sì ngbọ́ ohùn náà; pàápàá tí ó tún ní ìgboyà láti gbé ohùn náà sí’ta, fún àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), nígbàkugbà tí ó bá yẹ láti gbé ohùn náà jáde fún wa.
Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, MOA, ní àìpẹ́ yí, tún ti gbé ohun síta o! Ẹ gbọ́ bí wọ́n ṣe sọ́: Màmá sọ báyi, wọ́n ní:
“Pẹ̀lú àtìlẹyìn Ọlọ́run, mo lè fi dá yín lójú, Ọlọ́run dá mi lójú, 2025 yí, gbogbo Adelé wa, pátápátá, wọ́n ti wọ Sẹkitéríátì wa; wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí mú wá sí ojúṣe, Àlàkalẹ̀ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́.
Màmá tún tẹnumọ, wọ́n ní “Láìpẹ́ yí, 2025 yí ni o, kò yẹ̀ o, kò sì pẹ́ o; Ọlọ́run mọ ìgbà àti àsìkò o, mi ò tíì mọ̀ o, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ó máa ṣé.
Ẹ̀yin ẹ fọkàn balẹ̀.
Màmá tún wá sọ síwájú, ní àlàyé, wọ́n ní, “2025 yí, a mà máa gba àkóso gbogbo ohun-ìní wa – pátá – gbogbo bárékè wa, gbogbo ibodè wa, gbogbo pápákọ̀-òfúrufú wa, àwọn èbúté, gbogbo ohun-ìní wa, ohun-àmúṣògo wa, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ wa, gbogbo ohun ìníyelórí wa, gbogbo ẹ̀ la máa gba àkóso wọn, lágbára àṣẹ tí Ọlọ́run fi njẹ́ èmi ni; a sì máa lò wọ́n, a máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́bí Àlàkalẹ̀ Àtọ̀runwá tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún àwa I.Y.P. Àlàkalẹ̀ Àtọ̀runwá yẹn, kò yẹ̀.
Màmá tún wá sọ̀rọ̀ síwájú, wọ́n ní, “Àwọn tó wà nbẹ̀ [báyi], tó bá wù wọ́n, kí wọ́n fi sùúrù kúrò; a ti sọ fún wọn bí wọ́n ṣe máa fi sùúrù kúrò.
Tó bá sì wù wọ́n, kí wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ líle kó mú wọn kúrò. Èyí tó bá wù wọ́n ni; ṣùgbọ́n, wọ́n máa kúrò. Láìpẹ́ ni. Ọdún yí ni.
Nítorí ọ̀rọ̀ yí, gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, ẹ jẹ́ kí á máa fi ìdùnnú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ fi ojú sọ́nà, kí á sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè pé ayọ̀ wa ti dé.
Ẹ jẹ́ kí á kíyèsára, kí a máṣe gba ohunkóhun láàyè láti mú ọkàn wa kúrò nínú ìrètí yi: ìrètí ológo ni. Lọ́dún yí, láìpẹ́.