Ọ̀rọ̀ ti dójú ẹ̀, báyi o! Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, gbé ohùn jádé: Nigeria, Ẹ JÁDE KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ YORÙBÁ TÍ Ẹ GÉ MỌ́ ÌPÍNLẸ̀ NIGER YÍN àti ÌPÍNLẸ̀ KEBBI YIN!
Ọ̀rọ̀ àṣẹ rèé o, láti Democratic Republic of the Yoruba. D.R.Y
Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ti jáde kúrò nínú Nàìjíríà, pẹ̀lú Ìkéde Òmìnira, ní ogúnjọ́, oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún; bẹ́ẹ̀ náà ni a ti ṣe ÌPOLONGO ÌṢÈJỌBA-ARA-ẸNI wa ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí – ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún; a sì sọ, nígbà náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, pé gbogbo ilẹ̀ wa, pátá tí Nàìjíríà ti gé mọ́ ìpínlẹ̀ Niger wọn, àti Ìpínlẹ̀ Kebbi wọn, ni a ṣì máa gbà padà.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi, gbogbo Ìpínlẹ̀ Èkó, Ìpínlẹ̀ Ìbàdàn (èyí tí Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ npè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́); Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ìpínlẹ̀ Ondó; Ìpínlẹ̀ Èkìtì, àti Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (èyí tí òpùrọ́ Nàìjíríà fún lórúkọ Kwara, àti apá kan Kogi) ni a ti mọ̀ sí ilẹ̀ D.R.Y
Ṣùgbọ́n, a sọ níjọ́ náà, lọ́hun, pé, ara ilẹ̀ Yorùbá, tí ó jẹ́ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́, ṣùgbọ́n tí Nàìjíríà ti fi irọ́ kó mọ́ ìpínlẹ̀ Niger wọn, àti Ìpínlẹ̀ Kebbi wọn, ni a máa gbà padà o!
Àsìkò ti wá tó báyi – gbogbo nkan tó jẹ mọ́ Nàìjíríà, ní ìsàlẹ̀ Odò Ọya, Ó YÁ, ẹ kúrò níbẹ̀; Yorùbá dé, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, D.R.Y, dé, láti gba nkan wa padà!
A mọ àlà tí Olódùmarè fún wa o! Odò Ọya ni àlà wa; ohunkóhun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Odò Ọya, sí ìsàlẹ̀, ilẹ̀ Yorùbá ni! Kí ẹ gbọ́, kí ẹ má ṣe etí ọ̀gbọn-in!
Odò Ọya ni Àlà Ilẹ̀ Yorùbá, láti àtètèkọ́ṣe wá. Nítorí èyí, Nàìjíríà, gbogbo nkan tí ẹ nṣe ní gbogbo ilẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti Odò Ọya sísàlẹ̀, ṣùgbọn tí ẹ̀yin npè ní Ìpínlẹ̀ Niger, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!
Gbogbo ẹni tí ó wà ní, láti Odò Ọya sísàlẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Nàìjíríà ní ẹ dìrọ̀ mọ́, tí ẹ npera yín ní Ìpínlẹ̀ Niger, ó yá, ẹ jáde kúrò nbẹ̀; ilẹ̀ Yorùbá nìyẹn.
Nàìjíríà, gbogbo nkan tí ẹ nṣe ní gbogbo ilẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti Odò Ọya sísàlẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin npè ní Ìpínlẹ̀ Kebbi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀! Gbogbo ẹni tí ó wà ní, láti Odò Ọya sísàlẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Nàìjíríà ni ẹ dìrọ̀ mọ́, tí ẹ npera yín ní Ìpínlẹ̀ Kebbi, ó yá, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ilẹ̀ YORÙBÁ ni’bi tí ẹ wà yẹn.
Nàìjíríà, gbọ́ ìkìlọ̀ yí o! – gbogbo ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Odò Ọya, wá sísàlẹ̀, ilẹ̀ Yorùbá ni – Ẹ JÁDE KÚRÒ NÍBẸ̀ KẸ́Ẹ TÓ RỌ́RÀN! A nsọ fún yín báyi o!
Ilẹ̀ àjogúnbá ọmọ Yorùbá ni! Ilẹ̀ ÌRAN YORÚBÁ ni, ilẹ̀-Ìbílẹ̀ Yorùbá ni! Ọ̀run ti dìde; ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Babanlá wa; ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Àjogúnbá wa!
A mọ gbogbo àrékérekè tí ẹ ti ṣe! Láti ìgbà láíláí ni ó tí jẹ́ pé Odò Ọya ni gbogbo ayé ti mọ̀ sí Àlà Ilẹ̀ Yorùbá, tí ó sì hàn gbagede ní àwọn Àwòrán Àlà Ilẹ̀, láti ayébáyé; ṣùgbọ́n, torí pé ẹ̀yin bẹ̀rẹ̀ sí ṣe èrú, láti gba ilẹ̀ wa lọ́wọ́ wa, ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run kò fún yí ṣe, ẹ wá bẹ̀rẹ̀ sí ya àwọn àdàmọ̀dì Àwòrán Àlà Ilẹ̀ tí kò tọ́ka ibi tí Odò Ọya gbà kọjá, torí kí a má bàá fura pé ẹ ti ngé ilẹ̀ wa mọ́ ìpínlẹ̀ Niger yín, àti ìpínlẹ̀ Kebbi yín (èyí tí ẹ mú jádé lára Sokoto, tí ẹ wá mu pẹ̀lú ilẹ̀ Yorùbá to bẹ̀rẹ̀ láti odò ọya sísàlẹ̀, ẹ wá sọ pé Kebbi nìyẹn! Aà, kò níí dáa fún Ìran gbogbo yín! Ẹ KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ YORÙBÁ.
Ní ẹgbàá ọdún ó dín mẹ́ta-lé-lọ́gbọ̀n ni ẹ bẹ̀rẹ̀ àwọn àdàmọ̀dì Àwòrán Àlà Ilẹ̀ tí kò ní ìtọ́kasí Odò Ọya! Ibi tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ èrú yín nìyẹn – tí ẹ pe ibi kan ní “Ìpínlẹ̀ Kwara,” tí ó jẹ́ pé Ìṣèjọbá Ọ̀yọ́ ti ayébáyé, tí gbogbo àgbáyé gbọ́ òkìkí rẹ̀, ni ibẹ̀.
Nígbà náà, ẹ ti fi ọgbọ́n gé lára ilẹ̀ wa ọ̀ún pàápàá mọ́ èyí tí ẹ pè ní “North Western State,” níbi tí ẹ ti wá sẹ̀hìn mú Sokótó àti Niger jáde – ẹ ti nji díẹ̀díẹ̀ – ṣùgbọ́n a ti dé láti gba nkan wa báyi o.
Ìgbà tí ó wá di ẹgbàá ọdún ó-dín-mẹ́san, ni ẹ tún wá já lára Kwara mọ́ lára Sokoto, tí ẹ pèé ní “Kebbi”, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ tún mú lára Kwara ọ̀ún, tí ẹ fàá mọ́ apá kan Benue ní òdì kéjì ibi tí Odò Ọya ti dorí kọ ìsàlẹ̀ láti máa lọ sínú agbami Òkun, ẹ wá pè yẹn ní “Kogí”.
Ṣùgbọ́n a ti lẹ̀ ti gba èyí tí ó ṣe tiwa ní Kogi yẹn ná; ṣùgbọ́n èyí tí ẹ ti gé mọ́ “Niger” yín, àti mọ́ “Kebbi” yín yẹn, ó yá, àfira, Ẹ Jáde Kúrò Nbẹ̀!
Bóyá ó ṣeé ṣe kí ẹ ṣì máa díbọ́n bí ẹni tí etí rẹ̀ di: ẹ jẹ́ kí ó là o! Létí gbogbo àgbáyé lati nsọọ́ yí o: Nigeria àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ pé Nàìjíríà ni wọ́n dìrọ̀ mọ́, Ẹ JÁDE KÚRÒ LÓRÍ GBOGBO ILẸ̀ TÍ Ó TI BẸ̀RẸ̀ LÁTI ODÒ ỌYA WÁ SÍ ÌSÀLẸ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin npè ní ara Niger àti ara Kebbi – irọ́ ni o!
ILẸ̀ YORÙBÁ NI! Odò Ọya ni Àlà Ilẹ̀ Yorùbá, láti ayébáyé; gbogbo àgbáyé ló mọ̀; Ẹ JÁDE KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ WA!