Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè, Ìyá-Ààfin), ẹni tí Olódùmarè rán sí àwa ọmọ Yorùbá láti ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún wa, ti gbé ohùn síta fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) pé, Kò sí nkankan tó njẹ́ “warrior” mọ́ ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y); kí ẹnikẹ́ni máṣe pe ara rẹ̀ ní “warrior” mọ́! kí ẹnikẹ́ni má sì sọ pé àwọn ní “warrior” kankan ní ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y).
Ọ̀rọ̀ yí jẹyọ ní àìpẹ́ yí, nígbàtí Màmá wa, MOA, nbá àwa I.Y.P ti D.R.Y sọ̀rọ̀.
Màmá wa MOA fi yé wa pé, ìyàtọ̀ wà láarín ìgbà tí a nrin-ìrìn-àjò, àti ìsin-ìyí tí ó jẹ́ pé a ti kúrò ní ìrìn-àjo (movement), a ti wá di orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni (sovereign nation) báyi! Kí eku-ilé kó gbọ́, kó sọ fún t’oko; kí àdán ó gbọ́, kó rò fóóbẹ̀, ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, kí ẹnikẹ́ni kí ó máṣe kó èrò jọ mọ́, wọ́n kéré ni, wọ́n pọ̀ ni, ẹ máṣe kó èrò jọ dípò pé ẹ máa pè wọ́n ní “warrior”. Gbogbo irúfẹ́ nkan bẹ́ẹ̀ ti di ọ̀ràn-dídá lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni!
Oun tí ẹ ṣe ní àsìkò “movement” (ìjà-ngbara tàbí ìrìn-àjò sí òmìnira), ó yàtọ̀ sí ohun tí ẹ lè ṣe nígbàtí kò sí ní ìrìn-àjò tàbí ìjà-gbàrà mọ́, tí a ti wá di orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni báyi!
Ó ti di ẹ̀sùn-ọ̀ràn-dídá báyi, fún ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ní “warrior,” kò sí nkan tó njẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́; kò sí “warrior” ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ-ológun ti D.R.Y, èyí tí ó jẹ́ pé orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y ni ó gbà wọ́n síṣẹ́ ológun, kìí ṣe èyí tí ẹni kan kó jọ fúnra rẹ̀, tó nsọ pé “àwọn warrior òun nìyí”! Ó ti di ọ̀ràn-dídá láti kó “warrior” kankan jọ, ó ti di ọ̀ràn-dídá fún ẹnikẹ́ni láti sọ pé òun ní “warrior” ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ẹ ti ọwọ́ ọmọ yín bọ aṣọ, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nsọ pé ẹ ní “warrior.” Orílẹ̀-èdè olómìnira ni ẹ wà! – àyè kò gbà yín láti ní ọmọ-ogun kankan lábẹ́ yín!
Nítorí náà, Màmá wa, MOA, sọ pé, gbogbo ẹni bẹ́ẹ̀, ẹ ṣe àtúká gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ pé ẹ ní “warrior;” ẹ wó gbogbo ẹ̀ palẹ̀, pátápátá, kó máṣe tún gbérí mọ, láyé! Ẹ ò lè ní ọmọ-ogun kankan lábẹ́ yín, nígbàtí ẹ̀yin fúnra-yín wà lábẹ́ orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni. Ẹ lọ fi òpin sí irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Tí ó bá ní ẹnikẹ́ni tí ẹ fẹ́ ràn lọ́wọ́, pé fún ìgbé-ayé ara tiwọn, ẹ ní àyè láti ràn wọ́n lọ́wọ́ gẹ́gẹ́bí ẹnìkan, ṣùgbọ́n kìí ṣe pé kí ẹ kó “warrior” jọ, kí ẹ wá sọ pé ó ní iye-owó kan tí ẹ fi ngbé-wọn-ró lóṣooṣù gẹ́gẹ́bí “warrior” yín! RÁRÁ-O! Ọ̀ràn-dídá ni ìyẹn já sí, báyi, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Kò sí nkan tí ó njẹ́ ìjà-ngbara mọ́, ati di orílẹ̀ èdè D.R.Y.