A pẹ́ kó tó jẹun, kìí jẹ ìbàjẹ́

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Olódùmarè kẹ́ pẹ̀lú ohun àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí ní àgbáyé, iwájú ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) wà, gbogbo ohun tí ẹ̀dá nílò láti gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn ló wà ní orí ilẹ̀ wa.

Àwọn àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí tí orílẹ̀ èdè míràn kò ní ìdá kan rẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n sì ń gbé nínú ìfọ̀kànbalẹ̀, lọ́pọ̀lọpọ̀ ni Olódùmarè fún wa. Àwọn tí wọ́n fi ń ṣe títì ọlọ́dà, ọkọ̀ bààlúù, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, iná mọ̀nà-mọ́ná àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣé ti ilẹ̀ ọlọ́ràá ni kí a sọ ni, ilẹ̀ tó kún fún wàrà àti oyin, a ò nílò ajílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn. Bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè ṣe ìkẹ́ ìran Yorùbá pẹ̀lú ọpọlọ pípé.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) sọ láìpẹ́ yí wípé, kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti jìyà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Nípasẹ̀ àwọn ohun tí a ti mẹ́nubà yí, pẹ̀lú àwọn ohun mìíràn tí a kò dárúkọ, ìgbé ayé ìrọ̀rùn ló yẹ fún

ẹnìkọ́ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí àwọn amúnisìn so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́ tan, pẹ̀lú èròǹgbà láti pa ìran Yorùbá run, tí àwọn olóṣèlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà náà sì ń ṣiṣẹ́ tọ̀ọ́, èyí ló mú kí wọ́n máa fi ìyà jẹ àwa ọmọ Aládé.

Ìyà náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí púpọ̀ wa fi níláti fi ilẹ̀ babańlá wa sílẹ̀ láti lọ máa ṣe ẹrú àwọn amúnisìn, fúnra wa ni a tún fi ẹsẹ̀ wa rìn lọ bá wọn, ọ̀pọ̀ á tilẹ̀ tún ta ohun ìní rẹ̀, ó mà ṣe o!

Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé màmá wa dìde, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí, wípé kí a padà sí orírun wa, kí a sì gba ogún ìbi wa padà èyí tí àwọn amúnisìn ti fi ẹ̀tàn gbà lọ́wọ́ wa láti ọjọ́ pípẹ́.

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a wà ní ìdúró ṣinṣin àti ìmúrasílẹ̀ fún àjọyọ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti dúró, kí Olódùmarè kí ó pa gbogbo àwọn olùdènà, àwọn ìkà àti àwọn ọ̀dàlẹ̀ run.

Gbogbo àwọn ajẹgàba, kí ìparun dé bá gbogbo wọn, kí àwọn alákòóso wa wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso láìpẹ́ àti làì jìnnà pẹ̀lú ayọ̀ àti àlàáfíà, kí ìtura sì dé bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P. Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè mi Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá D.R.Y!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal