Màmá Ìran Yorùbá, Ẹni tí Olódùmarè rán sí wa láti ṣe iṣẹ́ ìgbàlà Òmìnira àti ìdándè fún ìlọsíwájú àti Ìdàgbàsókè ọmọ-Yorùbá, Ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti ṣe ìkìlọ̀ tó lágbára fún gbogbo àwa ojúlówó ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).
Wọ́n ní kò sí àwáwí kankan fún I.Y.P tó bá kọsẹ̀; I.Y.P tó bá ṣe ohun tí D.R.Y sọ pé kí a má ṣe. Màmá wa MOA sọ pé tí ó bá dé ojú ẹ̀, D.R.Y kò ní gbà, ìwọ tí ó jẹ́ I.Y.P, nípasẹ̀ jíjẹ́ I.Y.P o ní ẹ̀tọ́ sí àwọn nkankan, ṣùgbọ́n tí o ti wá lọ kọsẹ̀, wọ́n sọ pé kò sí àwáwí kankan tí a máà gbà láti fi ojú fo kíkọsẹ̀ tí ẹni náà ti kọsẹ̀.
Nítorí náà, wọ́n ní ìwọ tí o bá ṣe nkan tí D.R.Y ní kí a máṣe, tí o wá sọ pé ṣe ni o ò gbọ́, kò sí nkan tó jọ-ọ́! Kò sí pé ṣe ni kò sí iná-mọ̀nà-mọ́ná, òun ni o ò ṣe gbọ́, rárá o! tàbí o kò ní oore ọ̀fẹ́ sí ẹ̀rọ ayélujára ni o ò ṣe gbọ́, D.R.Y ò mọ̀ nípa ìyẹn rárá! Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́bí I.Y.P ti D.R.Y, o níláti fi ṣe iṣẹ́ ṣe, ní ìgbà gbogbo, láti mọ̀ọ́-mọ̀ máa wá àti láti máa ṣe àwárí nípa gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bí nkan ṣe nlọ nípa ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè rẹ̀, D.R.Y. Ojúṣe rẹ ni, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwárí rẹ̀, lóòrè-kóòrè.
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, tó bá wá sí ilé-ìwòsàn ní D.R.Y, tí wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò fún ẹ, tí wọ́n wá ri pé ohun tí ó nṣe ẹ́ ní àgọ́-ara jẹ́ àfọwọ́fà-àìgbọràn ìwọ fúnra rẹ, nípasẹ̀ GMO tàbí nípasẹ̀ abẹ́rẹ́-àjẹsára tí o lọ gbà, nígbàtí D.R.Y sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé kí á yàgò pátápátá fún GMO, àti fún oríburúkú abẹ́rẹ́-àjẹsára tí àwọn apani-máyọdà amúnisìn ngbé kiri, tí a sì ri pé lẹ́yìn ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìkìlọ̀ kí a màṣe gba nkan wọ̀nyí láàyè, ni ìwọ ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ gbàá, máṣe rò pé o lè wá lọ sí ilé-ìwòsàn D.R.Y lẹ́yìn àfọwọ́fà tìẹ, kó wá fẹ́ jẹ ànfààní ìwòsán-ọ̀fẹ́ lórí àìsàn tó jẹ́ àfọwọ́fà rẹ, rárá o! o ò lè wá jẹ ànfààní yẹn!
Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ pé kí á máṣe pàdí-àpò-pọ̀ mọ́ àwọn aríremáṣe nàìjíríà tí wọ́n njẹgàba sórí ilẹ̀ wa, tí wọ́n sọ pé àwọn nkọ́ ọmọ ní ilé-ìwé, lẹ́yìn ìgbàtí Olórí Ìṣàkóso Adelé ti sọ pé kí gbogbo ilé-ìwé ó sì wà ní títìpa ná; lẹ́yìn náà Màmá tún rán wa létí pé tí ọmọ tìrẹ bá ṣì nlọ sí ilé-ìwé lábẹ́ àwọn ajẹgàba wọ̀nyí, kí á lọ mú àwọn ọmọ náà kúrò, ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti mú ọmọ rẹ kúrò, D.R.Y kò fẹ́ gbọ́ pé ṣe ni o ò mọ̀! Gbogbo òbí bẹ́ẹ̀, ẹ ti kóbá ọmọ yín, kò lè rí ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní D.R.Y; bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kó bá ara yín, nítorí ẹ máa pàdánù lára àwọn ẹ̀tọ́ yín; Màmá sì nsọ pé kò sí àwáwí tí ẹ lè ṣe tí D.R.Y máa gbà.