Ẹ jẹ́ kí a ṣọ́’ra fún irúfẹ́ onjẹ tí a njẹ, ní àkókò yí. Nígbàtí a bá ti lé àwọn agbésùnmọ̀mí ìj’ọba Nàìjíríà kúrò l’orí ilẹ̀ wa tán, ìj’ọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá máa ri dá’jú wípé gbogbo ohun tí a máa máa jẹ s’ẹnu ní ilẹ̀ Yorùbá máa jẹ́ inkan tí kò l’ewu rárárárá.

Ẹ má gbàgbé wípé àwọn òyìnbó amúnisìn ní ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ọ̀nà tí wọ́n ngbà l’ati fa ikú fún ẹni t’ó wà l’orí ilẹ̀ ayé yí; pàápàá tí ó bá tún jẹ́ aláwọ̀dúdú.
L’ara ọ̀nà tí wọ́n fi nṣe iṣẹ́ búburú yí, ni kí wọn máa gbé ay’edèrú onjẹ, l’oríṣiríṣi, sí ọjà. L’ara ìwọ̀nyí ni ohun mímu tí ó dà bí èso [fruit drink] àti èso tí a kó wọ’lé l’ati ìlú òkèèrè [imported fruit]. Bẹ́ẹ̀ náà ni a rí oríṣiríṣi onjẹ míràn, gẹ́gẹ́bí ewé’bẹ̀, tí ó jẹ́ ay’edèrú bákannà.
Wọ́n máa npe àwọn ay’edèrú irú’gbìn tàbí ẹran tàbí ohun ọ̀gbin wọ̀nyí ní “genetically modified organisms” (GMO). Nít’orí náà, tí ẹ bá ti ngbọ́ “GMO,” ay’edèrú onjẹ l’ó njẹ́ bẹ́ẹ̀.
Èyí yàtọ̀ sí àwọn ohun ọ̀gbìn, tàbí ẹran, tàbí ẹja, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó jẹ́ wípé bí Olódùmarè ṣe dá wọn ni wọ́n wà, tí àwọn oní’ṣẹ́ ibi kòì tíì sọ wọ́n di GMO.
- Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Ṣe Òfin Oní’lé-Gbé’lé Ní Èkìti!
- Ọmọ Yorùbá Ṣe Ìkìlọ̀ Tí Ó L’agbára Fún Bill Gates !
- Ajílẹ̀ Aburú Ti Ba Nkan Jẹ́ Ní Ìlú T’ó F’ẹ̀gbẹ́ Tì Wá
- Ọmọ Yorùbá Ṣe Ìkìlọ̀, L’ẹẹ̀kan Si, Fún Òṣínbàjò
- Ilẹ̀ Yorùbá Kìí Ṣe Fún Àjèjì Kankan!

Àwọn tí ó wà gẹ́gẹ́bí Olódùmarè ṣe dá wọn yí, ni wọ́n máa npè ní “organic.” Ó dá wa l’ojú wípé, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ìgbà ni a ti máa ngbọ́ tí Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọ fún wa wípé, àwọn nkan Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (D.R.Y), wípé “organic” ni àwọn nkan wa máa jẹ́.
Inkan tí Màmá nsọ nípa rẹ̀ n’ìyẹn – wípé, a ò ní gba nkan ay’edèrú l’aàyè, nítorí àwọn nkan ay’edèrú wọ̀nyí máa nṣe ìpal’ara fún ọmọ ènìyàn.
Àwọn ìròyìn tí ó tún tẹ̀ wá l’ọwọ́ gbogbo, l’orí ọ̀rọ̀ yí, ni a óò máa mú wá sí etí-ìgbọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.





