Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹ̀lú ìlú, agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ṣùgbọ́n nígbàti wèrè bá jókòó sẹ́nu ọ̀nà olórí-pípé, pẹ̀lú ọpọlọ orí-pípé yẹn náà ni a máa fi lé wèrè lọ.
Ibi tí ọ̀rọ̀ ọmọ Aládé, ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), àti Nàìjíríà dé lónìí nìyẹn ọ̀rọ̀ ọlọ́pọlọ pípé àti aṣiwèrè ni.
Tí kìí bá ṣe ìwà aṣiwèrè, kí ló fa kí Nàìjíríà ṣì máa tan-ra wọn jẹ, tí wọ́n jóko lórí ilẹ̀ Yorùbá, lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ pé Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́?
Tí kìí bá ń ṣe àìnítìjú, kíló dé tí ìjọba Tinubú tí ó fipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ D.R.Y ṣe máa ta páálí ẹyin adìyẹ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin-àbọ̀ náírà fún àwọn òǹtajà, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òǹtajà ń tàá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín igba náírà? Báwo ni wọ́n ṣe fẹ́ jèrè?
Ìyẹn gan-an tiẹ̀ kọ́ ni kókó ọ̀rọ̀: kókó ọ̀rọ̀ ni pé, Nàìjíríà, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba! Ẹ̀ ń fi ìyà jẹ ọmọ Yorùbá lórí ilẹ̀ wọn! Ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ Yorùbá lẹ́kún; tó bá jẹ́ pé ìlú Nàìjíríà yín lẹ ti nṣe eléyi, kò kàn wá rárá.
Ìgbéraga àti àìnítìjú yín ló jẹ́ kẹ́ẹ gàba lórí ibi tí kì ń ṣe ilẹ̀ yín,ṣé ojú yín ló fọ́ tàbí etí yín ló di? Nítorí pé ẹni tí ojú rẹ̀ kò bá fọ́, á ti ríi pé Yorùbá kò sí lára nàìjíríà mọ́; ẹni tí etí rẹ̀ kò bá sì di, á ti gbọ́ pé Yorùbá ti kúrò ní Nàìjíríà;ṣùgbọ́n ó dàbí wípé ẹ ò lẹ́ni tó lè bá yín sọ̀rọ̀ tí ẹ máa gbọ́; nítorí èyí ni ẹ̀sín yín ṣe máa pọ̀ ní àìpẹ́ yí!
Olódùmarè, jọ̀wọ́ ṣe àṣepé ìgbàlà ìlẹ̀ Yorùbá àti Ọmọ Yorùbá kúrò lọ́wọ́ Nàìjíríà, ṣeé ní ojúkorojú, kí ìjọ àwọn ènìyàn yí le mọ̀ pé Ìwọ kìí fi idà tàbí ọ̀kọ̀ gbani là, nítorí ti Olúwa ni ogun náà, ó sì ti fa Nàìjíríà lé wa lọ́wọ́: wọ́n máa sá kúrò lórí ilẹ̀ Yorùbá, Yorùbá yíò sì ní ìsinmi títí ayé!