Àǹfààní tí ó pọ̀ ló wà lára àwọn oúnjẹ wa ti à ń jẹ ní ilẹ̀ Yorùbá, gbogbo àwọn oúnjẹ wa ni wọ́n máa ń ṣe ara lóore tí a bá pèsè wọn fún jíjẹ ní ọ̀nà tí ó tọ́.
Gbogbo wa ni a mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí a ń lo àgbàdo fún ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n èyí tí mo fẹ́ pe àkíyèsí wa sí ní apá ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa kii kà sí.
❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)Tí àgbàdo tútù bá ti jáde, gbogbo wa ni a máa ń ṣèé jẹ́ pẹ̀lú omi, tàbí kí á taá ní orí iná, a ó jẹ ẹ́ tán tí a ó sì sọ sùkù rẹ̀ nù.
A tún máa ń rẹẹ́ nínú omi gbígbóná dí ọjọ́ kẹta kí ó baà lè rọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti yín in kúrò lára sùkù tán láti lè fi ṣe ògì. Gbogbo wa ní a ní ẹ̀rọ nínú ilé ìdáná wa, tí a bá ti wa àgbàdo yìí kúrò nínú omi tí a fi rẹ ẹ́, a máa wá tún un fọ dáadáa pẹ̀lú omi tí ó mọ́, kí á wá bẹ̀rẹ̀ sí máa lọ ọ́ díẹ̀ díẹ̀ tí ó máa fi kùnà bí ìgbà tí a bá lọ ata ọbẹ̀.
Tí a bá ti lọ gbogbo àgbàdo náà tán, kí á wá bù omi sí orí ògì náà, kí á dé e mọ́lẹ̀ di ọjọ́ kejì, ògì wa ti dé nìyẹn o, tí ó máa rọra kan díẹ̀ lẹ́nu, èyí tí ó fi ṣe adùn nìyẹn.
Ohun tí mo fẹ́ fà yọ níbẹ̀ ni pé, tí a bá ti lọ ògì wa kùnà bí ata ọbẹ̀, kò sí ìdí fún wa láti máa fi àṣẹ jọ èérí kankan kúrò nínú ògì náà, nítorí pé, àgbàdo tí a ṣe ní omi gbígbóná jẹ tabi ti a ta á jẹ, a kò yọ èérí kankan kúrò ní ibẹ̀, nítorí èyí ni wọ́n ń pè ní odindi àgbàdo tí ó ní èròjà tí ó máa ń ṣe ara loore ninu.
Àbí ẹ kò kíyèsí àwọn ewúrẹ wa tí a máa ń fún ní èérí yìí jẹ ní bí ara wọn ṣe máa ń dán yọ yọ yọ?, àbí, ṣé ẹnikẹ́ni ń lo ìpara fún wọn ni bí?, tí wọ́n bá jẹ èérí tán, wọ́n máa tún bọ́ sí’nú igbó, wọn máa jẹ èwe tútù síi, irun ara àwọn ewúrẹ máa ń dán bí ẹnì pé ènìyàn fi àdí tàbí orí pa irun ara wọn ni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á kíyèsí i ìmọ̀ràn yìí.