- Home
- Ìpínlẹ̀
- Àwọn Ẹ̀ka D.R.Y
- Ẹ̀ka Ọdọ D.R.Y
- Services & Information
- General Data Collection Form
- IYP STUDENT WITHDRAWAL FORM
- FORMS & GUIDELINES FOR YORUBA TUTORIAL CENTRE
- Ètò ẹ̀kọ́
- Engineering
- Artisans
- Ètò Ìlera àti Ìwòsàn – Ìlera Lọrọ!
- Creatives Media / ICT
- Finance & Commercial Services
- Submit Your Business Proposal
- Àgbaṣẹṣe
- Àǹfààní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Tí Yorùbá
- Ìròyìn Òmìnira
- IYPDRYtv
- Resources
Eyi jẹ ìkan l’ara àgbékalẹ̀ ètò fun gbogbo ọmọ bíbí orílè-èdè Yorùbá ti a mọ si Blueprint.
Gẹ́gẹ́ bi mama wá, Ọmọ-Aládé Modupeola Onitiri-Abiola ṣe sọ wípé ko tun ni si òun ti ò njẹ “kosisẹ” tabi “òṣì” tabi tálákà láwùjọ ọmọlúwàbí mọ, nítorí náa, iforukosilẹ rẹ ṣe pàtàkì fun wa láti le fòpin si òṣì ati isẹ káàkiri orílẹ̀-èdè Yorùbá.
Ilẹ̀ Yorùbá kùn fún wàrà àti oyin pẹlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọpọlọ pípè àmọ́ tí ìlú mújẹ-mújẹ Nàìjíríà kọ jẹ kí ara ìlú mọ. Boju-boju ni wọn fi bo yín loju, Òun ti o nbẹ nilẹ Yorùbá nìkan-nìkan o to fun gbogbo ilẹ̀ Afíríkà.
Lati rí dájú pe ìdàgbàsókè ati Itesiwaju de ba ìlú wá ati ọrọ ajé wá, ìjọba nrọ ẹyin ara ìlú ti ẹ jẹ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Yorùbá, ki ẹ so’wọpọ pẹlu wa nípa fífi àwọn orúkọ yin pẹlu àlàyé àwọn oríṣiríṣi ìṣẹ ti ẹ yan láàyò, kí ó ba le rọrùn fún wa láti pèsè isẹ fún gbogbo wa.
Èmi ko ní iriri ko si nbẹ rárà!
Èmi ko gbọ èdè òyìnbó ko si nbẹ rárà!
Erongba wa ni lati jẹ orílẹ̀-èdè ti o ni idagbasoke julọ ni agbaye. À ko le ṣàṣeyọrí eyi laisi imọ, ọgbọn, ati oye yín; nitori náa, ẹ ba wá fi orúkọ yin ránṣẹ́. Ẹ jẹ ka so’wọpọ lati pèsè ọjọ ọla ti o dara fun awọn ọmọ wa ati awọn ìran ti nbọ lẹyin-wa-ọla!
Àkíyèsí Pàtàkì
1. Fọwọsi fọọmu yi gẹgẹbi a ṣe gbé kalẹ; Awọn aaye tí à sàmìnsí (*) jẹ dandan fún wa!
2. Rí dájú pé òtítọ́ ni gbogbo òun ti o fi ránṣẹ́ ki o ma ba pàdánù àǹfààní náa.
3. O gbọdọ jẹ ọmọ bíbí Yorùbá! Ẹnikẹ́ni ti o ba fi orúkọ rẹ silẹ – ti ki ńṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Yorùbá, ní à o yọ kúrò.
**Gbogbo òun èlò fún ìṣe yii (raw materials) gbọdọ wa làti inú ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Yorùbá. Tí ko bá wa sí ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, ko gbọdọ kọja àpapọ̀ orílẹ̀-èdè ti o wa ni Afíríkà (ti o si jẹ orílẹ̀-èdè ti o fọwọsi òmìnira Yorùbá).
Díẹ̀ lára àwọn Ànfàní
Ilana Iṣowo to mu èrè dánì
Gba ìmọ̀ràn iṣowo ati ọgbọ́n-kun-ọgbọ́n lati ọdọ awọn amòye tí ìjọba yió pèsè l'ọfẹ
Ìrànlọ́wọ́ Ìjọba
Ko dabi ti tẹlẹ mọ! Iwọ ko ni lati dàrú ẹru ayé mọ! Ìjọba yio pese Ìrànlọ́wọ́ fún ẹ!
Fọọmu imọran iṣowo
Jọ̀wọ́ fọwọsi fọọmu ni isalẹ lati fi imọran iṣowo rẹ silẹ si Ijọba D.R.Y.
F.A.Qs
Yes, You can apply. The Democratic Republic of the Yoruba is for the Indigenous People of Yoruba irrespective of where you are, you entitled to all the benefits.