Iṣẹ́ wa fún ‘lẹ̀ wa,
Fún Ilẹ̀ ìbí wa,
K’á gbega, k’á gbega,
K’á gbega f’aiyé rí.
Ìgbàgbó wa ni ‘pé,
B’a ti b’ẹrú l’a b’ọmọ
K’á ṣ’iṣẹ́, k’á ṣ’iṣẹ́
K’a ṣ’iṣẹ́ k’a jọ là.
Ìsọ̀kan àt’òmìnira,
Ni ẹ jẹ́ k’á mã lépa, ‘Tẹ̀síwájú f’ọpọ̀ ire
Àt’ohun t’ó dára.
Ọmọ Òduà dìde,
Bọ́ sí’pò ẹ̀tọ́ rẹ,
Ìwọ ni ìmọ́lẹ̀
Ògo Adúláwọ̀.