Báwo ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ṣe wá kàn wá báyi o? Kò kàn wá, rárá, ṣùgbọ́n kí á lè fi mọ̀ ọgbọ́n àrékérekè tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun máa nlò láti jẹ gàba lé orí ènìyán dúdú!

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Pín Sórí X
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi hàn wípé ohun tí Nàìjíríà sọ wípé tiwọn, kìí ṣe tiwọn, nítorí wípé, kí ni ànfààní wípé o sọ wípé o ní epo rọ̀bì ṣùgbọ́n àwọn òyìnbó ni ónpa àṣẹ fún ẹ, bí o bá lè fọ epo rọ̀bì rẹ tàbí o kò lè fọ̀ọ́ !

Èdùmarè ni ó ṣe ògo wa fún wa ní Orílẹ̀-Èdè olómìnira tiwantiwa ti Yorùbá; tí a kò sì sí ní abẹ́ Nàìjíríà mọ́! Ojú ni alákàn fi nṣọ́ orí – èyí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìtọ́sọ́nà wa nínú gbogbo ohun tí a bá nṣe!

A kò gbọ́dọ̀ gbà mọ́, láyé, kí òyìnbó kankan, tàbí ilé-iṣẹ́ òyìnbó kankan ó lọ́wọ́ nínú ìgbé ayé ọmọ Yorùbá, ní orí ilẹ̀ Yorùbá, èyí tí ó jẹ́ wípé òun ni wọ́n nṣe fún Nàìjíríà, tí ó fi jẹ́ wípé Nàìjíríà ní epo ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ láti fún’ra wọn ṣètò bí wọ́n ṣe máa máa fọ epo wọn fún’ra wọn!

A kò gbọ́dọ̀ fi àyè kankan rárá gba àwọn aláwọ̀ funfun kankan rárá láti tún kó wa lẹ́rú gẹ́gẹ́bí wọ́n ti kó àwọn babanlá wa ní ẹrú l’ayé ijọ́-un.