Ìwà rere jẹ́ ọ̀nà tí èèyàn yàn láti lo ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Yorùbá ṣe máa ń p’òwe wípé ìwà rere lẹ̀ṣọ́ ènìyàn.

Láti kékeré ló ti yẹ kí a máa kọ́ àwọn ọmọ wa láti máa hu ìwà rere, àwọn Yorùbá náà ni wọ́n tún máa ń p’òwe pé inú ilé lati ń kó ẹ̀ṣọ́ r’òde.

Àwọn ọmọdé náà lè kọ́ láti máa sọ pé “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun,” wọ́n sì lè mọ bí èèyàn ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíràn. Tí àwọn  ọmọ bá mọ̀ pé ohun tí àwọn bá ṣe máa nípa lórí ìdílé wọn, ilé ìwé wọn, aládùúgbò wọn, tàbí àwùjọ wọn, wọn ò ní máa ro tara wọn nìkan, wọ́n á sì máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn mìíràn láǹfààní.

A gbọ́dọ̀ kọ̀ àwọn ọmọ wa láti máa ṣe dáadáa sí áwọn ènìyàn, kí wọ́n má máa ro ti ara wọn nìkan, kí wọ́n ní ìfẹ́ ọmọlakejì kí wọ́n sì máse ìmẹ́lẹ́. 

Láti kékeré ni a ti gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ wípé, kò dára láti mú ohun tí kì í ṣe tẹni, ìwà ojú kòkòrò àti olè ní èyí jẹ́ tí kò sì dára.

Gbogbo àwa tí a ti dàgbà pàápàá àwa ọ̀dọ́ tí ìwà rere ti sọnù lọ́wọ́ wa látàrí ìdojúkọ wa lọ́wọ́ àwọn ìjọba ìlú agbésùnmọ̀mí tí a ti kúrò nínú rẹ̀, a fẹ́ fi àkókò yìí sọ fún yín pé yóò sàn kí ẹ lọ gbé ìwà ọmọlúwàbí yín níbi tí ẹ bá gbé e kọ́sí  kí ẹ sì gbé ìwà ọmọlúwàbí wọ̀, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa nígbà gbogbo pé ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá  kò ní sí àyè fún ìwà ìbàjẹ́ kankan bó tií wù ó mọ,tí màmá sì tún máa ń sọ wípé ẹni tí ó bá da ọwọ́ rú, a ó dà ẹsẹ̀ rẹ̀ rú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 

Nítorí náà gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò, kí a sì ṣe àtúnṣe níbi tí ó bá yẹ, ẹ jẹ́ kí a ríi dájú pé a jẹ́ olódodo nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe nítorí wípé, òdodo níí gbé orílẹ̀ èdè lékè.