Ẹni tí ó yẹ fún ọgbà ẹ̀wọn tó ń mú’ni sí àtìmọ́lé ọlọ́pàá. Ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó ń jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ń kọjá àyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ àwọn babańlá wa.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti orí Ayélujára X, ni fọ́nrán kan tó ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe kó obìnrin, ọkùnrin àti ọmọ-kéékèèké papọ̀ sínú àtìmọ́lé kan-náà ní àgọ́ ọlọ́pa ní Márọkọ́.
Kí wá ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ ajẹgàba nàìjíríà kà sí wọn lọ́rùn? Wọ́n ní wọ́n wà ní’ta lálẹ́. Ó màṣe o, Ọmọ Yorùbá kò tún le rìn ní àláfíà ní orí ilẹ̀ àwọn baba rẹ̀ mọ́. Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), níbikíbi tí a bá ti rí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bí eléyìí, ẹ jẹ́ kí a máa ya àwòrán, tàbi ṣe fídíò tí ó gbé ojú àwọn ọ̀daràn ọlọ́pàá agbésùnmọ̀mí nàìjíríà báyi sí’ta, kí á sì ṣe àkíyèsí agbègbè náà.
Yàtọ̀ sí pé ìwà ọ̀daràn gbáà ni bí àwọn ọlọ́pàá apanilẹ́kún jayé nàìjíríà ṣe wà lórí ilẹ̀ Yorùbá títí di àkókò yí, ìwà títẹ ẹ̀tọ́ ẹni lójú mọ́lẹ̀ ni wọ́n hù yí, èyí kò leè ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y rárá níwọ̀n ìgbà tí ẹni náà kò bá ti hu ìwà ọ̀daràn.