Ọ̀mọ̀wé Vandana Shiva ṣí aṣọ lójú eégún tí wọn ń pè ní Bill Gates àti ọnà àrékérekè tó gbà láti sọ ara rẹ̀ di ògúnná gbòngbò nínú ohun èlò ayárabíàṣá kọ̀mpútà, tí ó sì ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti máa jẹ gaba bí ọlọ́rọ̀ àti gbajúmọ̀ l’ágbàáyé.
Obìnrin yìí sọ̀rọ̀ nínú fọ́nrán kan lórí ayélujára pé kò sí ohun kan tí Bill Gates f’ọwọ́ ara rẹ ṣé, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣirò kan ni ó kọ àlàkalẹ̀ tí wọ́n fí ṣe ohun èlò kọ̀mpútà náà tí onímọ̀ ẹ̀rọ ohun èlò kọ̀mpútà kan sí ṣeé jáde, sùgbọ́n ọnà ẹ̀bùrú ni Bill Gates fi ra ohun èlò iṣẹ́ kọ̀mpútà yìí lówọ́ rẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ̀ta dọ́là. Ó di olọ́rọ̀ rẹpẹtẹ nípa pínpín àwọn ohun èlò yìí sí oríṣiríṣi ọ̀nà láti máa tàá.
Ó tún sọ pé ní ìpàdé àkọ́kọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Ìṣòwò Àgbáyé ní Singapore ní wọ́n ti fun ní ààyè nípa owó orí, èyí wá fun ní ànfàní èrè púpọ̀ láti di ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ.
Obinrin ọ̀mọ̀wé yìí ni Bill Gates máa ń ná owó àánú rẹ̀ sí ibi tí ìdánilójú wà fun láti rí ọjà rẹ̀ tà ni, tí ó túmọ̀ sí pé oníṣòwò ní Bill Gates, kìí fi owó ṣe àánú rárá.
Àwọn òtítọ́ tí ó tún ń farahàn nípa Bill Gates yí ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé okùnrin yìí kìí ṣe onínú rere tàbí onínú dídùn tí ń f’owó ṣe àánú, oníṣòwò lásán tí kò ka ẹ̀mí ènìyàn sí rárá ni, o máa ń fí ìtọrẹ tirẹ̀ fún èèyàn tàbí ìlú ní àgbáyé níbití ó bá mọ̀ pé òun ti máa ṣ’òwò-j’èrè ni.
Ara àwọn ọ̀rọ̀ tí màmá wa alálùbáríkà, iránṣẹ́ Olódùmarè fún òmìnira àwa ọmọ Yorùbá, Olóyè ìyá-àfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiola máa ń sọ nípa gbígba owó ìtọrẹ àánú pàápàá láti ilẹ́ òkèèrè níyì, nítorí oko ẹrú míràn ní.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ màmá wa, Orílẹ̀ Èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá kò ní gba owó ọ̀fẹ́ tàbí ìtọrẹ àánú kankan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tàbí orilẹ̀ èdè, tàbí Àjọ, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò níí yá owó lọ́wọ́ Àjọ tàbí bánkì kankan ní àgbáyé, ọmọ Àládé kò ní padà lọ sí oko ẹrú keji láílaí, a máa ṣiṣẹ́, a ó pèsè ohun tí a nílò, a ó sì lo ohun tí a bá pèsè, nítorí Olódùmarè kẹ́ àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye tí ó ta yọ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ ológo tí wọ́n sì ní làákàyè àti orí pípé.