Nípa awuyewuye tó kó ọkàn I.Y.P s’ókè láì pẹ́ yìí, tí màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá fi dá ti ọ̀tún fún ọ̀tún àti òsì fún òsì ni kí àwọn méjèèjì tí ọ̀rọ̀ kan fi ẹ̀rí tí oníkálukú wọ́n ní ránṣẹ́ sí olórí Adelé, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́.

Màmá wa MOA tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n ní àwọn méjèjì ṣẹ àwọn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fi ọ̀rọ̀ náà dá ìpòrúru ọkàn fún I.Y.P. 

Màmá wa, òrìṣà òmìnira ilẹ̀ Yorùbá (MOA), tun sọ pé ẹnìkan máa pe àwọn méjèjì náà ní ọjọ́ àbámẹ́ta, tíí nṣe ọjọ́ keje oṣù Ọ̀pẹ, ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún, kí wọ́n ṣe àlàyé fún ẹni náà, ìdí tí wọ́n fi fi àyè sílẹ̀ fún nkan tó wá da ọmọ Aládé láàmú yí.

Tí ó bá wá di ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹjọ oṣù Ọ̀pẹ, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélogún, wọ́n ó wa ṣe àlàyé àbábọ̀ rẹ̀ fún I.Y.P.

MOA wa tún sọ fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) pé, àrà ète àwọn ìkà tó jẹ́ ọtá òmìnira Yorùbá ní láti fí ọ̀rọ̀ náà dá èdè-àì-yedè sílẹ̀ láàrín àwon tó súnmọ́ àwọn kí wọ́n lè fí dojú ìjà kọ àṣepé òmìnira wa ní.

Mama wa MOA ní, kí àwa ọmọ Aládé má fò’yà, nítorí eruku lásán làsàn ní, Olódùmarè ti parí iṣẹ́ Rẹ̀, kò sí ẹnití ó lè da dúró.

Ọ̀rọ̀ ìtùnú ní èyí jẹ́, ọmọ Aládé, ẹ jẹ́ kí a ma yọ ayọ̀ òmìnira.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal