A ti gbọ́, a sì ti mọ̀, pé àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe ohun aburú lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sí àwa aláwọ̀dúdú, pàápàá sí àwa Ìran Yorùbá; wọ́n ké wa kéré lọ́pọ̀lọ́pọ̀, wọ́n sì wá ṣe bí ẹni pé àwọn ni ó là wá lójú, tí eléyi kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárárárá.
Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ (Old Ọyo Empire), gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀, kò ní ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní gbogbo àgbáye: nínú ọlá, nínú òkìkí, nínú ọrọ̀, nínú agbára; ó ga ju ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ga ju ilú Amẹ́ríkà lọ, ṣùgbọ́n àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ l’oní pé bẹ́ẹ̀ l’ó ṣe rí.
Wọ́n tẹ orí àwọn ènìyàn wa ba; wọ́n mú wọn kí wọ́n kọ ogo, àṣà, ohun-ẹ̀mí àti ẹ̀kọ́ abáláyé wọn sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ti òyìnbó bíi pé òun ló dára jù.
Gbogbo wa ni a ti mọ èyí, gẹ́gẹ́bí ìyànjú tí òyìnbó amúnisìn, Lord Macaulay, gba Ilé-Ìgbìmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní ẹgbẹ̀sán ọdún ó lé márun dín-lógójì, ní ọjọ́ kéjì, oṣù èrèlé, ní ọdún náà l’ọhún, pé kí wọ́n gba ti ọwọ́ wa, kí àwọn sì fi ti àwọn rọ́pò rẹ̀.
Iṣẹ́ ibi yí ni wọ́n ṣe, de’bi tí ó jẹ́ pé, l’oní, ohun tí àwọn èèyàn mọ̀ gẹ́gẹ́bí ìtàn wa, ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí òyìnbó amúnisìn ti gbé tiwọn lé wa lọ́wọ́, ó wá dà bí ẹni pé a ò ní ayé rere kan tẹ́lẹ̀ kí òyìnbó ó tó dé! Irọ́ nlá gbáà!
Síbẹ̀ náà, àyípadà búburú tí àwọn òyìnbó ìránṣẹ́ àṣìtáánì wọ̀nyí ṣe fún wa, ìtàn àyípadà ọ̀ún, pàápàá, fi hàn pé ilẹ̀ Yorùbá, ilẹ̀ ológo, kò gbẹ́hìn nínú àdàmọ̀dì ọ̀làjú àti “ìdàgbàsókè” òfegè tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́.
Gẹ́gẹ́bí fọ́nrán kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe fi yé’ni, ẹgbàá ọdún ó-dín mẹ́ta-lé-l’aádọ́run, ni ìjọba Gẹ̀ẹ́sì, ìjọba amúnisìn, gbé ọ̀pá àṣẹ (ó mà ṣe ò!) fún Ọba Aríwàjoyè Kíní ti Ìlú Ọ̀ffà ní agbègbè Ìṣèjọba Ọ̀yọ́; èyí gba omijé lójú ẹni, òyìnbó gbé “ọ̀pá àṣẹ” fún ọba ní Ìṣèjọba Ọ̀yọ́! Ìṣèjọba Ọ̀yọ́ ti gẹ̀ẹ́sì fún’ra rẹ̀ kò tó bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àwọn amúnisìn ọ̀ún ó tó wá fi arékérekè wọn tẹ orí àwọn babanlá wa ba!
Síbẹ̀, ògo ṣì nyọ l’ara àwọn baba wa wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ògo wo l’ó wà nínú ipò ẹrú?
Gẹ́gẹ́bí a ṣe gbọ́ nínú fọ́nrán náà, gbígbé ọ̀pá àṣẹ fún ọba Aríwàjoyè mú kí ipò òmìnira ìlú Ọ̀ffà ó túbọ̀ gbòòrò si! Òmìnira nínú ipò ẹrú!
Ní ọdún tí ó tẹ̀le ni ọkọ̀ ojú-irin dé ìlú Ọ̀ffà. Eléyi mú kí Ọ̀ffà ó di ibùdó pàtàkì nínú ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ fún kíkó erè-oko l’ati ibi-kan dé òmíràn, eléyi sì mú kí ìdàgbàsókè ti olóyìnbó-dé yí kí ó dé bá ìlú Ọ̀ffà!
Àdàmọ̀dì Ìtàn irúfẹ́ eléyi ni ó wà káàkiri ní ilẹ̀ Yorùbá! Ìtàn tí ó bẹ̀rẹ̀ L’ẸYÌN ìgbà tí àwọn òyìnbó ti tẹ orí àwọn baba wa ba tán! Ìtàn tí ó purọ́ pé a ò ní ògo kankan, pé ènìyàn lásán ni wá (tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀) kí àwọn òyìnbó ó tóó dé; ìtàn tí ó sọ pé òyìnbó l’ó là wá l’ojú!
Tí eléyí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Àwa ni a là òyìnbó l’ojú! Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti rí ohun tí ó njẹ́ pé ìlú dàgbà-sókè; ṣùgbọ́n, l’oní, wọ́n ti tún ìtàn wa kọ! Ṣùgbọ́n, àwa ọmọ Aládé máa tún àtúnkọ ìtàn náà, a máa tunkọ padà; a máa kọ Òtítọ́ Ìtàn wa gidi, gẹ́gẹ́bí Ìyá Wa ṣe sọ fún wa, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, pé a máa fùn’ra wa kọ Ìtàn wa – òtítọ́ ìtàn!
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, ẹ jẹ́ kí á dìde, kí a mọ̀ pé ojú-ogun l’a wà, kìí ṣe ti ọ̀kọ̀ tàbí idà (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa dáàbò bo ilẹ̀ wa, a dẹ̀ máa ṣe olùgbèjà fún ìṣèjọba-ara-ẹni wa); ṣùgbọ́n kí á gbárùkù ti Ìjọba-Adelé wa, kí á máṣe b’ojú wẹ̀yìn; a ti já’de kúrò nínú ìgbèkùn nàìjíríà, a ti kúrò nínú nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó-lé-méjìlélógún, a sì ti ní ìjọba tiwa, ìjọba Democratic Republic of the Yoruba, láti ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí: ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún!
Orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni wá; a ò sí lábẹ́ nàìjíríà mọ́: Ṣèyí Mákindé, gbọ́ran kóo kúrò nínú ilé-iṣẹ́ wa ní Ìbàdàn; Jídé Sanwó-Olú, gbọ́ran, kí o jáde kúrò nínú ilé-iṣẹ́ wa ní Ìkẹjà; Adémọ́lá Adélékè, la etí ẹ! Yé ṣe bí adití: ìjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀: kó ẹrù ẹ (máṣe mú ẹrù-ìjọba wa mọ o!) ṣùgbọ́n kó ẹrù ẹ, kóo jáde kúrò l’oríkò ilé-iṣẹ́-ìjọba wa ní Òṣogbo!
Ìwọ Abdulrahman Abdulrazaq, jáde kúrò lóríkò ilé-iṣẹ́ wa ní Ìlọ́rin; Ododo, kúrò lórí àga-ìjóko wa ní Lọ́kọ́ja; Oyèbánjí, kúrò ní’bi tí kì nṣe tìẹ tóo jóko sí ní Adó-Èkìtì; o mọ̀ pé óò ní ẹ̀tọ́ kankan mọ́ ní’bẹ̀; ìwọ Ayédatiwa, olè lo jẹ́ ní’bi tóo jóko sí ní Àkúrẹ́ yẹn, o dẹ̀ mọ̀, ẹ̀wọ̀n àgbáyé ndúró dè ẹ́: jáde, kúrò ní Alágbàká; ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbá l’ó ni’bẹ̀!
Ìwọ Dàpọ̀ Abíọ́dún, yé ṣe orí-kunkun, má sọ pé ó di ìgbà tí wọ́n bá fún ẹ ní àṣẹ láti òkè, o mọ òfin; kúrò lórí ìjóko tí kì nṣe tìẹ – ìjóko ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbá nìyẹn!
Gbogbo yín ẹ jáde!