Ìran mi kò ní parun láéláé! Gbólóhùn yí jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí màmá MOA ma ń tẹnu mọ́.
Ìdí pàtàkì tí màmá, Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la ṣe ń tẹnu mọ ọ̀rọ̀ yí ni, bí àwọn amunisìn ṣe ń hùwà burúkú láti pá àwa ọmọ aládé rún kí wọn ba a lè gba ilẹ̀ wá mọ́ wá lọ́wọ́.
Ìwà búburú yí ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti ìgbà ayé àwọn babanla wá. Nítorí Èdùmàrè ló jogún ilẹ̀ wa fún wá láti ìgbà ìwáṣẹ̀.
Wọn pèrò, wọ́n sì mu sì ojú ìṣe, láti gba gbogbo ohun tí a fi ń ṣe ọlá, ọlà, àti ògo. Nítorí pé wọn bá wa gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè, tó lajú jùlọ tó sì gbajú gbajà ni Áfríkà nígbà náà. Wọn kò rí atọrọjẹ kankan, bẹ́ẹ̀ni wọn kò rí olè laarin wa.
Èyí jẹ́ òtítọ́ tí ìkan nínú àwọn amúnisìn náà sọ fún àwọn tó ran nísẹ́. Lẹ́yìn ìgbà ti wọn gbọ́ ìròyìn yí ni àwọn ènìyàn burúkú wọnyi dé pẹ̀lú ọ̀nà arékérékè wọn láti bá wa dòwò pọ̀. Láì mọ̀ wípé aṣekú pàni ẹ̀dá ni wọ́n.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwà àgàbàgebè àti kópa nínú ìṣe ìṣàkóso, wọ́n kọ́ ilé ìwé, lai mọ̀ wípé wọ́n fẹ́ gba èdè àti àṣà wa ni, wọ́n sì ki ọwọ́ bọ àwọn ọrọ̀-ajé wa pẹ̀lú ojúkòkòrò àti wọ̀bìà, wọ́n sì n jí nkan ọnà wa.
Àwọn ètò ìlera ni wọ́n ti’wọ́ bọ̀ pẹlu èrò ibi, láti pa wá rún, nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára. Bẹ́ẹ̀ ni wọn ṣe’kú pani pẹ̀lú òògùn tí wọ́n fi sí àwọn irúgbìn ìgbàlóde. Wọ́n gbé àwọn òṣèlú kalẹ̀ láti má a ṣe aṣojú fún wọn kí wọ́n le máa ṣe ìnilára fún àwọn ará ilu.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó fi àánú rẹ̀ hàn sí wa, tó gbé màmá wa, Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la dídé ni déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí fún ìgbàlà àwa ọmọ aládé. Màmá dúró gbọn-in gbọn-in lórí ẹsẹ̀ wọn méjèèjì wípé láyé, ojú kò gbudọ̀ rí ibi lẹ́ẹ̀kẹ́ta. Ìran àwọn kò ní parun. Ó di èèwọ̀.
Òun ló jẹ́ kí wọn máa lo gbogbo ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn láti jìjà òmìnira orílẹ̀ èdè àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), tí ó sì yọrí sí rere nipa ìkéde òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y.), èyí tó wá yé ni ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún.
A sì ṣe ìbúra-wọlé fún Ààrẹ wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawalé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ní ọjọ́ kejìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ sì ti bẹ̀rẹ̀ ni orílẹ̀ èdè wa fún ìgbádùn gbogbo àwa ọmọ aládé.
Èyí gangan ló kán eegun ẹ̀yìn àwọn amúnisìn àti ìṣàkóso agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, tí a ti jáde kúrò nínú rẹ̀ yí. Wọn kò ní gbéri mọ́ láṣẹ Èdùmàrè. Ìpínyà àwa àti àwọn aríremáṣe Nàìjíríà jẹ́ fún láéláé. Ìbáṣepọ̀ wa ti dópin.
Ní báyìí, màmá wa MOA ti bá wá ṣe àgbékalẹ̀ ètò tí kò ní ṣe-é wó lulẹ̀ títí láé, nípasẹ̀ Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún wa, nípasẹ̀ wọn.
Gbogbo àwa ọmọ aládé gbúdọ̀ mọ àwọn iṣẹ́ takuntakun tí màmá wa ti ṣe, kí a sì gbárùkù ti àwọn Adelé ̀láti ṣe iṣẹ́ papọ̀, fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè àti màmá MOÀ fún àṣeyọrí iṣẹ́ náà.