Olódùmarè má jẹ̀ẹ́ kí ayé wa dàbí ìlú aríremáṣe nàìjíríà, ìlú tí wọ́n ń fi ìwà ibi yangàn tí wọ́n sì ń gbilẹ̀ nínú rẹ̀, oníkálukú ló ń ṣe òfin lọ́wọ́ ara rẹ̀, òfin kò sí fún olówó, tálíkà nìkan ni ó wà fún, èyí wá fún kálukú láàyè láti ma pa èlòmíràn l’ẹ́kún jayé.

Nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti gbọ́ nípa arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ruth Ogunlẹyẹ tó jẹ́ ọmọ ológun ìlú apanilẹ́kún jayé nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n tó ti kọ̀’wé fi iṣẹ́ sìlẹ́ látàrí bí àwọn tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun ṣe ń yọọ́ lẹ́nu láti hu ìwà tí kò tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

Ní oṣù kínní ọdún tí a wà yí ní Ruth Ogunlẹyẹ fi ẹ̀sùn kan àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ níbi iṣẹ́ ológun wípé wọ́n ti fi àyé sú òun níbi iṣẹ́ ọ̀hún, àwọn náà ni I.B Abdulkareem, G.S Ogor àti  I.B Solebo.

Ó ṣe àlàyé wípé èyí tí ó ń jẹ́ I.B Abdulkareem ti ṣe ìkọlù sí òun láì mọ’ye ìgbà, bíi kó fi ipá fún òun ní abẹ́rẹ́, ìgbà mìíràn kó lé òun jáde nínú ilé, ó sì ti fi ìgbà kan mú òun lọ sí ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú alárùn ọpọlọ tí wọ́n sì dá òun dúró síbẹ̀ fún àìmọye oṣù lẹ́yìn tí òun kọ̀ láti báa lòpọ̀. 

Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Ìṣègùn tó kọjá yí ni ọ̀gá àgbà tó ń rí sí ìbáṣepọ̀ àwùjọ ní ilé iṣẹ́ ọmọ ológun agbésùnmọ̀mí nàìjíríà Onyema Nwachukwu wípé lẹ́yìn ìwádi lorísìírísìí, àwọn ríi pé Abdulkareem kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí Ogunlẹyẹ fi kàn án àti pé àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe ní ilé ìwòsàn kan ní Abuja fihàn pé Ogunlẹyẹ kò pé tó nípa ti ìlera. 

Arábìnrin náà ti wá ké pe àwọn ilé iṣẹ́ ológun agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti fi èsì ìwádìí tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà léde fún àgbáyé. 

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.

Iṣẹ́ àwọn apanilẹ́kún jayé nàìjíríà nìyẹn, kí wọ́n sọ ọmọ ológo di ìdàkudà. Ṣùgbọ́n, a dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà, kí àlàáfíà Olódùmarè máa bá màmá wa gbé títí láé. 

Nítorí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kò ní sí àyè fún irú ìwà ibi bí eléyìí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, tí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tó gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, yóò gba ìdájọ́ tó tọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.