Ìròhìn búburú kan g’orí afẹ́fẹ́ báyii láti ìlú Nàìjíríà, pé ilé ìwé girama alájà méjì kan tí orúkọ rẹ̀  ńjẹ́ Saint Academy, ti wó lulẹ̀. Ìṣèlẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ẹtì, ni ọwọ́ agogo bíi mọ́kànlá òwúrọ̀ ní àkókò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ńṣe ìdánwò lọ́wọ́. 

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ilé ìwé náà wà ní ìlú Busa Buji ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Jos, ní ìpínlẹ̀ Plateau ní Nàìjíríà. Ìròhìn yí fi yé wa pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ akẹ́kǒ ló wà lábẹ́ ilé tí ó wó náà, tí wọn kò tíì yọ wọ́n jáde.

Ọ̀rọ̀ yìí gb’omijé lójú ènìyàn bíótilẹ̀ jẹ́ kìí ṣe orílẹ-èdè Democratic Republic of the Yorùbá ló ti ṣẹlẹ̀. Bí àwọn tó ńṣe ìjọba kò bá ti ṣe ẹ̀tọ́ nítorí wọn kò nífẹ́ẹ àrá ìlú, oríṣiríṣi ǹkan búburú báyii ni á  ma ṣẹlẹ̀. 

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

A ò fi yọ̀ wọ́n, rárá o! Ṣùgbọ́n, ní àkọ́kọ́, ó dájú, ìjọba Nàìjíríà kò ṣe àbẹ̀wò tí ó yẹ nígbàtí wọ́n nkọ́ ilé náà, nítorí ìwà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti olè jíjà ti ba ayé Nàìjíríà jẹ́, láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí dé gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba, bẹ́ẹ̀ni ẹ̀mí ènìyàn kò jọ wọ́n lójú. Ètò ìdóòlà ẹ̀mí lásìkò pàjáwìrì kò f’ẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá. Àfi Ọlọ́run nìkan ló lè kó àwọn ọmọ náà yọ.

Orílẹ̀-èdè Yorùbá ní ètò rere fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ àti olùgbé inú rẹ̀; kò ní sí àyè àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí ìwà ọ̀lẹ lẹ́nu iṣẹ́ nítorí ẹ̀ẹ̀méjì loṣù ni a ó maa gba owó, kò sì ní jẹ́ owó kékeré. 

Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ kọ́lé yíò rí owó láti ra ohun ìkọ́lẹ̀ tí ó dára láti dènà ilé wíwó ati fífi ẹ̀mí ṣòfò.

Lórí ètò ẹ̀kọ́, gégébí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá ti jẹ́kí a mọ̀, àwọn ètò àti ìlànà ẹ̀kọ́ tí ó dára yàtọọ̀ ni ti D.R.Y. Àwọn ilé ìwé wa yíò rẹwà pẹlú ààbò tí ó dájú fún àwọn olùkọ́ àti gbogbo akẹ́kọ. A fi nsọ ọ̀rọ̀ tiwa ni o, a ò fi yọ àwọn ẹ̀dá tí abúrú yí ṣẹlẹ̀ sí rárá.

Gbogbo àwa ojúlówó  ọmọ Yorùbá níláti mọ̀ dájú pé àwọn ajẹgàba ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà mọ̀ọ́mọ̀ ńfi ẹ̀mí ènìyàn ṣòfò nítorí ẹ̀mí eniyan kò jọ wọ́n lójú.

Bí ó tilẹ̀ ṣàìṣe ilẹ̀ wa ni ó ti ṣẹlẹ̀, a mọ̀ wípé ète nàìjíríà ni láti pa ọmọ Yorùbá run, nítorí wọ́n jọ ńṣisẹ́ pọ̀ pẹlú àwọn tó fẹ́ pa Yorùbá run láti gba ilẹ̀ wa. Ìdí rèé tí wọ́n fí kọ̀ láti fi orílẹ-èdè wa sílẹ̀ láti ìgbà tí ìjọba Adelé wa ti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe, ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún.

Ó wá yẹ báyìí kí àwa ọmọ Yorùbá dìde láti gba ara wa nítorí tí àwọn Adelé wa bá ti wọ ilé iṣẹ́ ìjọba wa, ìgbádùn  ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ wa, pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun ìkẹ́kọ̀ọ́ ìgbàlódé àti àwọn ǹkan amáyé dẹrùn fún àwọn ọmọ ilé ìwé gbogbo, ni ìlànà wà nílẹ̀ fún.

Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá níláti dìde kí á múra sílẹ̀ fún àjọyọ̀ wa tó ti wọlé dé tán  yìí.