Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, olè tí ó fi ipá àti àrékérekè gba ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ilẹ̀ káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì jẹgàba sí’bẹ̀ pẹ̀lú ìkónil’ẹrú amúnisìn tí wọ́n nṣe káàkiri àgbáyé nígbànáà-l’ọhún, títí di àkókò yí pàápàá, ti wá j’ọwọ́ àwọn Erékùṣù Chagos báyi, fún Orílẹ̀-Èdè Mauritius, èyí tí ó wà ní Agbami-Òkun apá ìlà-oòrùn Áfríkà.
Ṣebí Mauritius l’ó kúkú ni Àwọn Erékùṣù ọ̀ún tẹ́lẹ̀! – ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn olè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé àwọn fẹ́ fún Mauritius ní òmìnira tí wọ́n béèrè fún ní ẹgbàá-ọdún ó dín méjìlél’ọgbọ̀n, wọ́n ní àyàfi tí Mauritius bá fi àwọn Erékùṣù Chagos sílẹ̀ fún Gẹ́ẹ̀sì láti máa tẹ̀síwájú ìṣàkóso ní’bẹ̀! À b’ẹòri!? L’ó wá di, màá kúrò ní’lé ẹ, ṣùgbọ́n ìyàwó ẹ máa bá mi kúrò ní t’ipá!
Bí Mauritius ṣe gba Òmìnira Àbùkù ní’jọ́ náà l’ọhún n’ìyẹn!
Ṣùgbọ́n báyi, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti dá ìṣèjọba àwọn Erékùṣù Chagos padà fún Mauritius, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ní àwọn ẹrù sí’bẹ̀.
Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́bí ìkànnì YouTube tí a ti rí ìròyìn náà (Firstpost) ṣe sọ, Ó ṣe jẹ́ ní àkókò yí gan-an gan ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ̀wọ́ nkan f’onínkan?
Ó yẹ́ kí àwa náà, ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba, (D.R.Y) ó béèrè irú ìbéèrè yí, ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olódùmarè, ó yé wa! – Ṣé a ti wá ri, báyi, irú iṣẹ́ tí àdúrà àwa ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá nṣe! Lóotọ́ àti ní Òdodo, àwa ni Ìmọ́lẹ̀.
Ohun tí àwọn ará-ìlú Mauritius kò rí gbà l’ati iye ọdún wọ̀nyí wá, òun ni wọ́n mà rí wẹ́rẹ́ yíi, nípasẹ̀ Ìf’arahàn Ore-Ọ̀fẹ́ Olódùmarè l’orí àwa I.Y.P ti D.R.Y !