Fọ́nrán kan tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ló ṣe àfihàn ọkọ̀ ojú omi kan, tó ń lọ láàárín agbami òkun, pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn nínú rẹ̀, ó dájú pé àwọn èrò ọkọ̀ ojú-omi náà ti pọ̀jù, ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí èyí, ìrìn-àjò wọn ọ̀hún kò rọgbọ rárá.

Lójijì ni ọkọ̀ ojú-omi yí fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó wá ṣí’dí díẹ̀, àfi ìgbà tí a rí àwọn ẹ̀dá alààyè tí ọkọ̀ yí rọ́ wọn dà sínú agbami! 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fọ́nrán náà kò sọ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ti wáyé,ṣùgbọ́n àwọn aláwọ̀ dúdú ni gbogbo wọn! Èyí ṣe’ni  láàánú lọ́pọ̀lọpọ̀ torí a mọ̀ pé irúfẹ́ ohun báyìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá náà ń dojúkọ, látàrí bí ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ṣe ń fi ìyà jẹ́ wọ́n nígbà tí a sì wà papọ̀. 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, apaná ògo Nàìjíríà ṣì nfi ipá àti agídí  jẹgàba sorí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), síbẹ̀ a fẹ́ kí gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) mọ̀ pé láìpẹ́ àti láìjìna, Olódùmarè máa jẹ́ kí á rí ẹ̀yin wọn; wọ́n máa sá kúrò pẹ̀lú ìtìjú. 

Nítorí èyí, a rọ gbogbo àwa I.Y.P, ẹ má ṣe fi ẹ̀mí yín w’éwu mọ́, ìgbà díẹ̀ ló kù, tí àwọn ìjọba adelé wa máa wọ inú ilé-iṣẹ́ ìjọba gbogbo ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

A dùpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, Ẹni tí ó lo Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fún iṣẹ́ ribiribi yí.

Democratic Republic of the Yoruba