Àbá ní ńdi òtítọ́; ojo ni kì í jẹ́ ká da
Ẹ jẹ́ kí á máa fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀lé ohun tí ó bá ti jẹ mọ́ ìgbé-ayé wa gẹ́gẹ́bí Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y).
Èyí ṣe pàtàkì, kí á lè mọ ẹ̀tọ́ wa nígbà-gbogbo, kí á sì mọ ojúṣe wa bákannáà.
Ní àìpẹ́ yí ni Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran-Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fi yé wa pé, gbogbo òbí tí ó jẹ́ I.Y.P ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti mú ọmọ wọn kúrò ní ilé-ìwé níwọ̀n-ìgbà tí àwọn agbésùnmọ̀mí ajẹgàba ṣì ń tẹ̀síwájú láti ma ṣe ètò ilé-ìwé lọ ní orí-ilẹ̀ D.R.Y, lẹ́yìn tí Olórí Adelé ti sọ pé kí àwọn ilé-ìwé ní D.R.Y ó wà ní títìpa, tí Màmá MOA náà sì ti sọ fún wa pé kí a mú àwọn ọmọ kúrò ní ilé-ìwé ajẹgàba Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè wa D.R.Y, pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò pàdánù ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní D.R.Y, àti pé òbí náà, pàápàá yóò pàdánù lára àwọn ẹ̀tọ́ tirẹ̀ gẹ́gẹ́bí I.Y.P.
Ní ọjọ́’Rú, Ogúnjọ́ Oṣù Bélú, Ẹgbàá-Ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, nígbàtí Màmá wa ńbá wa sọ̀rọ̀ ní àjọ̀dún ọdún kéjì tí a ti ṣe ìkéde òmìnira wa kúrò nínú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, èyí tí a ṣe ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, Ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógun, ni Màmá wa tún sọ̀rọ̀ síwájú lórí ọ̀rọ̀ yí, tí wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn òbí bẹ́ẹ̀ pé, kìí ṣe owó ilé-ìwé nìkan ni wọ́n máa san fún ẹ̀kọ́ ọmọ wọn ní D.R.Y, ṣùgbọ́n wọ́n á tún san owó gbogbo ohun èlò ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ tó wà ní ilé-ìwé máa jẹ ìgbádùn rẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò ní wà ní ọ̀fẹ́ fún ọmọ tiwọn tí wọ́n kọ̀ láti yọ kúrò ní ilé-ìwé ní àkókò ìjẹgàba Nàìjíríà yí.
Lára nkan wọ̀nyí ni, ẹ̀rọ ayára-bí-àṣá tí àwọn ọmọ ilé-ìwé máà gbà, owó “wifi” tí orílẹ̀-èdè wa máa fún àwọn ọmọ ilé-ìwé lọ́fẹ; bẹ́ẹ̀ náà ni owó láti lọ ṣe ìbẹ̀wò-ẹ̀kọ́ èyí tí ó jẹ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ tókù.
Kìí tún wá ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n irúfẹ́ ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ní ànfààní ẹ̀yáwó tí ó bá fẹ́ kàwé kọjá ipele ìgboyè-kíní ní fásitì; òbí rẹ̀ máa san’wo gbogbo owó àwọn ǹkan yí.
Yàtọ̀ sí gbogbo ìwọ̀nyí, nígbàtí ọmọ náà bá pé ọmọ-ọdún mọ́kànlélógún, ó ti ní ẹ̀tọ́ láti ní ilẹ̀, dandan sì ni pé kí ó ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n irúfẹ́ àwọn òbí yìí máa san’wó fún ilẹ̀ náà ni, nígbàtí àwọn ọmọ tókù bá ngba tiwọn ní ọ̀fẹ́ láti ọ̀dọ̀ ìṣàkóso D.R.Y.