Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá ààfin) gbé ìkìlọ̀ síta lẹ́ẹ̀kan si wípé kí àwọn òbí lọ kó àwọn ọmọ wọn kúrò ní ilé ìwé, ṣùgbọ́n kò pọn dandan o, nítorí pé oníkálukú lóní ẹ̀tọ́ lati se ohun to ba wùú.
A kò le máa fi owó ara wa ra wàhálà sí ara wa lọ́rùn, nípa sísan owó ilé ìwé àwọn ọmọ wa fún àwọn AGBÉSÙNMỌ̀MÍ.
Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) tí ó bá kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ yi, yóò pàdánù lára àwọn àǹfààní rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi I.Y.P. Irúfẹ́ òbí bẹ́ẹ̀ yíò sì san owó ilé-ìwé àwọn ọmọ tí kò mú kúrò báyi; owó náà sì ju ti àjòjì lọ.
Gbogbo ọmọ Yorùbá lóní àǹfààní láti ṣe èyí tí o wùú, ṣùgbọ́n kí ó faramọ́ èrè rẹ̀. Ẹ má ṣe gbàgbé wípé àsìkò tí àwọn ọmọ dúró sí ilé yìí, ki wọ́n lo àsìkò náà láti kọ́ èdè Yorùbá, tó jẹ́ èdè abínibí wa.
Kíni àǹfààní ètò ẹ̀kọ́ tí àwọn amúnisìn ṣe agbátẹrù rẹ̀ tó sì jẹ́ wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò le lo ọpọlọ wọn láti ṣe àgbékalẹ̀ ohun tí wọ́n ń kọ́ ní ilé-ìwé ọ̀hún.
Àlàkalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) jẹ́ èyí tí kò sí ní ibikíbi ní àgbáyé gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ.
Ẹ̀kọ́ tí yóò wúlò fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè D.R.Y ni àwọn ọmọ wa yóò kọ́ ní ilé ìwé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a gbọ́ràn kí a má ṣe lòdì sí eyí. Orílẹ̀ èdè D.R.Y kò ní gbé ìgbésẹ̀ tó lè pa ẹnikẹ́ni lára. Fún àǹfààní ara wa ní o.