“Ẹ má bí’nú pé l’aìpẹ́ díẹ̀ s’ẹhìn, ẹ ò rí àyè lọ s’orí ilé-iṣẹ́ ayélujá’ra wa.
Oní’lé ilé-iṣẹ́ ayélujá’ra wa fún’ra rẹ̀ ni ó ní ìṣòro, tí ó sì gbàá ní ọpọ̀lọ́pọ̀ àkókò l’ati yan’jú rẹ̀, kọjá bí a ṣe l’erò lọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìṣòro náà jẹ́ ohun tí kò ṣe àjòjì iṣẹ̀lẹ̀ ní orí ayélujára, síbẹ̀, inú wa kò dùn sí bí ó ṣe pẹ́ kí ilé-iṣé Onílé ọ̀ún tó gbé’ra nlẹ̀ l’ati wá nkan ṣe si; nítorí èyí ni a ti ṣe wá kó ilé-iṣẹ́ ayélujá’ra wa lọ sí ọ̀dọ̀ Onílé míràn.
Àìsí lórí afẹ́fẹ́ fún ìgbà púpọ̀ yí, tún dá lóri pé a fẹ́ jẹ́ kí fọ́ọ̀mù tí ẹ fi ngbé orúkọ àti ẹni tí ẹ jẹ́ wọ’le, kí ó túbọ̀ rọ’rùn síi, gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe béèrè.
Jíjẹ́ kí ó rọ’rùn síi yí, wá túmọ̀ sí pé ẹ tún máa tún àwọn orúkọ yín àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ tún máa wá gbe wọ’lé l’akọ̀tun; àìjẹ́bẹ́ẹ̀, á di pé èyí tí àwọn kan ti gbé wọ’lé tẹ́lẹ̀ kò ní ṣeé papọ̀ mọ́ èyí tí àwọn míì nínú wa ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbé wọ’lé nísiìyí: kò ní b’ara mu!
A dúpẹ́ l’ọwọ́ yín fún ìbánigbọ́ràn ti ẹ bá wa fi gba ọ̀rọ̀ yí, a sì dúpẹ́ fún títẹ̀síwájú nínú àtìl’ẹhìn yín fún wa.”