Wọ́n ní tí ènìyàn bá ní ìkà méjì, áá fi ìkan ṣe ara rẹ̀.
Òwe Yorùbá
Òun l’ó bá ọ̀rọ̀ àwọn oyìnbó tí wọ́n rò wípé àwọn ni Ọlọ́run alààyè tí ó lè pa, tí ó sì lè jí dìde; òun l’ó bá ọ̀rọ̀ wọn dé.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XBí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé, l’akọ́kọ́ ná, àwa aláwọ̀dúdú ni àwọn òyínbó wọ̀nyí kó’ríra rẹ̀, tí wọ́n sì máa ngb’èrò abúrú sí l’ati ìgbà dé ìgbà; sí’bẹ̀, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ìgbà náà l’ó jẹ́ wípé wọ́n máa nṣe abúrú wọ̀nyí sí gbogbo àgbáyé, pẹ̀lú àwọn fún’ra wọn tìkara wọn – nít’orí wípé, l’aárín ara wọn, àwọn kan rò wípé àwọn ni àwọn di ayé mú, àti wípé kò sí bí àwọn kò ṣe jẹ́.
T’ìtorí èyí l’ó ṣe jẹ́ wípé, tí nkan wọn bá ti gùn wọ́n báyi, oríṣiríṣi ìkà sí ara wọn àti sí ẹlòmíràn ni wọ́n máa máa ṣe!
Ká Ìròyìn: Ọmọ Yorùbá Ẹ Jẹ́ Kí A Kíyèsíara Nípa Òògùn Lílò
Èyí ni ó fa ọ̀rọ̀ ìdá’jú tí àwọn tí ó wà ní ilé iṣẹ́ ìjọba tí ó nbo’jútó ìpèsè omi fún ará ìlú ní ìpínlẹ̀ Idaho ní ìlú Amẹ́ríkà, tí wọ́n tún ndá’jú àwọn ènìyàn wọn dé’bi wípé kí wọ́n gbé àgbéka’lẹ̀ kan sí’ta tí ó sọ wípé àwọn á dín omi tí ó nlọ sí àwọn ibi tí wọ́n tí nṣe àgbẹ̀, àwọn á dín’kú! Tìt’orí kíni o? Ìyẹn ni a ò wá mọ̀! Ṣé oní’kà máa nní ìdí tí ó fi nṣe ìkà ní?
Ṣùgbọ́n a mọ̀ wípé, l’ara àwọn òyìnbó wọ̀nyí náà ni a ti rí àwọn kan tí ó burú ju ìy’ókù wọn, àti wípé àṣìtáánì ni àwọn wà l’ayé l’ati máa ṣ’iṣẹ́ fún; irú wọn ni àwọn tí ó sọ wípé ẹni tí ó wà l’ayé ti pọ̀ jù, àfi kí àwọn ríi wípé kí àwọn dín ọmọ ènìyàn kù ní ìgboro ayé!
Ọ̀nà tí wọ́n dẹ̀ fi nṣe eléyi ni wípé kí wọn máa hu ìwà ìkà, kí wọ́n máa ṣe oríṣiríṣi nkan tí ó le fa ikú fún ọmọ ènìyàn, kí iye ènìyàn tí ó wà l’ayé kí ó le dín kù!
Tani kò ṣàì mọ̀ wípé tí kò bá sí omi tó ní’bi tí wọ́n bá ti nṣ’oko, àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ní’lò ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ omi, àti àwọn ohun ọ̀sìn, bákannáà, yíò kó sí wàhálà! Tani kò mọ ọgbọ́n kí a fi ẹran sí ẹnu, k’ó sì pòórá!
Ká Ìròyìn: Àjàkálẹ̀-Àrùn Ún Ṣẹ́ Yọ N’ílùú Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Yorùbá
Bẹ́ẹ̀ wọ́n mọ̀ wípé ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ilé-iṣẹ́ tí wọ́n tí nṣe ẹran sí’nú agolo ni ó wà kàákiri ìlú Amẹ́ríkà, tí ó sì jẹ́ wípé, nínú iṣẹ́ ẹran ṣíṣe yí, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ kẹ́míkà ni ó máa njá’de ní’bẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìdọ̀tí ilé-iṣẹ́ ẹran ṣí’ṣe, tí àwọn omi ìdọ̀tí wọ̀nyí sì máa nṣàn lọ sí àwọn ibi t’ó ti lè ṣe ìpal’ara fún ọmọ ènìyàn!
Tí kò bá wá sí ọ̀pọ̀ omi t’ó mọ́ gaara l’ati máa lò ní àwọn oko, ó tú’mọ̀ sí wípé àwọn omi ìdọ̀tí tí ó l’oró wọ̀nyí á máa ṣe ìpal’ara fún ọmọ ènìyàn, tí kò sì sí omi gidi l’ati fọ nkan mọ́ tí kò fi ní sí àwọn ìdọ̀tí olóró wọ̀nyí l’awùjọ
Ẹ jọ̀wọ́, kíni ànfààní gbogbo ẹjọ́ wẹ́ẹ́wẹ́ tí a nrò yí?
Ànfààní rẹ̀ ni wípé, kí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, lè mọ̀ wípé, ayé yí kò rí bí a ti máa nròó o!
Àwọn àṣìtáánì, tí ó gbé ara ènìyàn wọ̀, tí wọ́n sì nṣe iṣẹ́ tí àṣìtáánì bàbá wọn rán wọn, wọ́n wà nínú ayé yí, bẹ́ẹ̀ ni Orílẹ̀-Èdè Yorùbá níl’ati ri wípé, a ò bá irúfẹ́ wọn d’òwò pọ̀, l’ayé!
Ṣe bí a mọ̀ wípé, l’ẹhìn Olódùmarè, Yorùbá Ni!