Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Olódùmarè dá ní àrà ọ̀tọ̀, ipò Kínní ni ìran Yorùbá wà, látàrí àwọn ohun àrà tí Olódùmarè dá s’órí ilẹ̀ Yorùbá.
Láìpẹ́ yìí ní a gbọ́ nípa igi ọ̀pẹ kan tí ó ní orí márùndínláàádọ́ta,tí a bá wo igi náà láti ìsàlẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ní’pele-ní’pele ló wà ní apá òkè. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ wípé, igi yí kìí so ẹyin, ṣùgbọ́n ikin ifá ló máa ń so. Ikin ifá ni àwọn babańlá wa máa ń lò láti dá ifá.
Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ẹ mọ̀ wípé àwọn òyìnbó amúnisìn yí ti ṣàwárí ibi tí igi yìí wà, a tilẹ̀ tún gbọ́ wípé wọ́n gbé àwọn irin iṣẹ́ wá síbẹ̀ èyí tí wọ́n lò láti fi mọ iye tí igi náà jẹ́, paríparí rẹ̀ wá ni wípé, gbogbo èso tí wọ́n bá ní ìdí igi yí ní ọjọ́ náà ni wọ́n kó lọ.
Àwa ọmọ Yorùbá, àkókò ti tó láti jí lójú orun wa, púpọ̀ àwọn ohun àrà meèrírí bí eléyìí ló wà lórí ilẹ̀ wa tí àwa tí a ní gan-an kò sì mọ̀ọ́ débi wípé a óò mọ ìwúlò rẹ̀, sé ẹ rí bí àwọn amúnisìn wọ̀nyí se ń kó àwọn ohun ìbílẹ̀ wa lọ, tí wọ́n sì ń fi ayédèrú tiwọn rọ́pò fún wa.
Ṣùgbọ́n kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde láti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn amúnisìn wọ̀nyí.
Nítorí náà, àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People IYP), ẹ má jẹ̀ẹ́ kí a gba ìgbàkúgbà láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni èyí tí ó leè mú kí a máa gbé àwọn ìṣẹ̀ǹbáyé wa lé àwọn àjòjì lọ́wọ́ tàbí kí a máa fi àṣírí rẹ̀ hàn wọ́n.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ kí a ní ìfẹ́ ara wa ká sí fi ìmọ̀ wa s’ọ̀kan, nítorí pé ìfẹ́ ni àkójá òfin.