Ọwọ́ tí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá gbé, ara rẹ̀ ló fi ń nà o. Ọ̀rọ̀ yí ní ṣe pẹ̀lú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, níbi tí a ti rí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ báyìí pé, àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti pa ó kéré tán bílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn.
Wọ́n ní àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ní Áfríkà nítorí pé wọn kò jẹ́ ǹkankan, wọn kò ní ìwúlò kankan, bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní ipa kankan lórí ọrọ̀ ajé ní àgbáyé.
Arákùnrin náà sì tún tẹ̀síwájú pé, àwọn yíò ṣe ìwádìí àti dídán àwọn ènìyàn wò ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ tí Bill Gates sọ pé, àwọn yóò pa bílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn run.
Wọ́n tún sọ pé, àwọn ti dá ilé-iṣẹ́ àìmọye sílẹ̀ tí ó ń pèsè oríṣiríṣi oògùn tí ó leè fa àrùn jẹjẹrẹ àti àwọn àìsàn ase’kúpani lọ́kanòjọ̀kan.
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a kíyèsàra gidigidi. Ọdẹ ìparun ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń dẹ fún àwa adúláwọ̀ lójoojúmọ́.
Ẹ jẹ́ kí a máa kíyèsí àwọn ohun tí a bá ń jẹ àti oògùn lílò.
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ lérò pé, ẹ wà ní òkè òkun, pé ẹ̀ ńgbádùn, tí ẹ wá ń ṣe àtakò lórí ìrìn-àjò Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, ṣé ẹ ti wá ríi báyìí pé inú òjìji ikú ni ẹ̀yin náà wà.
Fún ìdí èyí, a kò gbọ́dọ̀ fi àkókò ṣòfò rárá, bíkòsepé kí a dìde láti sa gbogbo ipá wa, kí a sì ti àwọn adelé wa lẹ́yìn.
Ní kété tí Olódùmarè bá ti bá wa sí àwọn olóríburúkú tí ó ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa nídìí, tí àwọn adelé wa sì ti wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba ní ìpínlẹ̀ wa kọ̀ọ̀kan, ìdẹ̀rùn dé fún wa nìyẹn.
Ẹ wo àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé báyìí, ṣùgbọ́n kìí se fún àwa ìran Yorùbá ó, nítorí pé Olódùmarè tí gba àwa ìran Yorùbá lọ́wọ́ àwọn asekúpani wọ̀nyí.
Nítorí náà, àwa ọmọ I.Y.P ti D.R.Y, àánú ńlá ni a rí gbà ó, nítorí pé, ìran tí Olódùmarè yọ́nú sí ni àwa ìran Yorùbá.
Ìdí nìyí tí ó fi gbé ìránṣẹ́ rẹ̀ dìde fún wa ni déédéé ìgbà yí.
Màmá wa olóríire, ẹ seun lọ́pọ̀lọpọ̀; àwa ìran Yorùbá mọ rírì iṣẹ́ ribiribi tí ẹ ṣe fún wa ò.