Gbogbo òbí tó jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) tó gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) sọ ní ọjọ́ kẹta oṣù Bélú ẹgbàá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún pé kí wọ́n mú àwọn ọmọ wọn kúrò ní gbogbo ilé ìwé agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y, máa ṣe ìforúkọ sílẹ̀ àwọn ọmọ náà fún àǹfààní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, gẹ́gẹ́bí ó ti wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé MOA lọ́wọ́ fún àwa ìran ọmọ aládé.
Màmá wa MOA ní ìwé ìforúkọsílẹ náà kò ní pẹ́ jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), o sì ṣe pàtàkì láti fi orúkọ àwọn ọmọ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí àwọn alákoso wa yíó nílò rẹ̀ láti mọ iye àwọn ọmọ tó yege fún ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nípa ìgbọ́ràn òbí wọn, kí ètò lè máa tẹ̀síwájú lóri ọ̀rọ̀ ẹ̀kò ọ̀fẹ́ náà.
Ṣe a ri bayii bí ìgbọràn ti ṣe pàtàkì to? Màmá wa ní iye àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọ́n gbọ́ran láti kó wọn kúrò ní ilé ìwé agbésùnmọ̀mí nàíjíria nìkan ló ma ní ẹ̀tọ́ sí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkàwé gboyé àkọ́kọ́ ní fásitì, pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ tí yíó tẹ̀lée.
Àwọn òbí tó ṣàìgbọràn yíó sanwó ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú owó ohun èlò ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n gbà ní ọ̀fẹ́. Kò tán síbẹ̀ o, owó tí wọ́n á san yíó pọ̀ ju ti àjèjì lọ, àwọn òbí yí tún níláti san owó ilẹ̀ àwọn ọmọ náà tí ọjọ́ orí wọn bá ti pé ọdún mọ́kánlelógún, ṣùgbọ́n tí ó sì jẹ́ ọ̀fẹ́ nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso D.R.Y láti fún wọn nílẹ̀ ní kété tí wọn bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kánlelógún.
Ó wa ṣe pàtàkì, bí màmá wa ṣe sọ, fún gbogbo àwa I.Y.P láti máa wo ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àwa ọmọ Yorùbá, iypdryTv fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn àti àlàyé nípa orílẹ̀ èdè wa ki a lè mọ bí ohun gbogbo ṣe nlọ ní ilẹ̀ wa àti àwọn ojúṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́bí ọmọ orílẹ̀ èdè rere.
MOA ní ayè kò sí fún wa láti rìn tàbí sáré, bíkòṣe kí a fò, nítorí ìjẹgàba àwọn aríremáṣe nàìjíríà tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀ èdè, sùgbọ́n tó jẹ́ ètò àwọn amúnisìn lásán tí wọ́n npè ní nàìjíríà. Nítorínáà kò sí àkókò, a máa ṣiṣẹ́ gidi ni láti ri dájú pé orílẹ̀ èdè wa di àwòkọ́ṣe rere ní gbogbo àgbáyé.