Jẹ́jẹ́ ni wàhálà máa ń jókòó tí àwa ìran Yorùbá sì máa ń lọ fi gọ̀ǹgọ̀ fàá. Ṣebi àwọn àlejò tí àwọn babańlá wa gbà mọ́ra tí wọ́n sì tún fún wọn láàyè láti máa jayé fàmílétè-n-tutọ́ ló kó àwa ìran Yorùbá sínú wàhálà tí a bá ara wa lónìí yìí, tí kì bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí kí a padà sílé, tó sì gbé ìránṣẹ́ Rẹ̀ dìde, màmá wa, ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti yọ wá kúrò nínú ìgbèkùn, dájúdájú, lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí àkókò tí a wà yí, ìran Yorùbá Kò bá di ohun ìgbàgbé pátápátá.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rí fọ́nrán obìnrin kan, a ò lè sọ pé ọmọ Yorùbá ni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí àwọn ọmọ àlè bíi irú rẹ̀ pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n èdè Yorùbá ló ń sọ lẹ́nu, obìnrin náà ni a rí bí ó ṣe ń jó, tó sì ń yọ̀ mọ́ àwọn ọmọ fúlàní méjì tí ọjọ́ orí wọn kò tíì lè ju bíi ọdún mọ́kànlá sí méjìlá lọ, ní agbègbè wọn, bẹ́ẹ̀ ló ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé kí ni ìdí tí wọn ò fi di irun? Lójú kan náà ló sì mú àwọn ọmọ fúlàní yìí lọ sí ilé onídìrí.
Ṣé a ti rí bí àwa ọmọ Yorùbá ṣe ń ní ìfẹ́ àfẹ́jù? Bí ó ti ń bẹ̀rẹ̀ rèé ó, kẹ̀rẹ̀-kẹ̀rẹ̀, àlàbọrùn yóò wá di ẹ̀wù mọ́ wa lọ́wọ́, ṣé kò sì ọmọ Yorùbá kankan ní agbègbè obìnrin yìí tó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ irú eléyìí fún, tó fi wá di ọmọ fúlàní lásán-làsàn?
Irú wọn ló máa ń dàgbà tán, tí wọn a máa pe ara wọn ní ọmọ Yorùbá, àwọn ni yóò wá máa ṣe alamí ní orí ilẹ̀ wa láti kó ogun jà wá lẹ́yìn wá ọ̀la.
A ń fi àkókò yí sọ fún gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) tí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) pé, iyán wa ti di àtúngún, ọbẹ̀ wa sì ti di àtúnsè nítorí pé, orílẹ̀ èdè D.R.Y kò ní fi àyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rárá, ṣé ìfẹ́ a máa fọ́’ni lójú ni?
Bí ìfẹ́ bá sì wà fọ́ ẹ̀yin ọmọ àlè ilẹ̀ Yorùbá lójú, kò tún gbúdọ̀ di yín létí, ìdí nìyí tí a fi ń sọ fún yín báyìí pé, ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, ohun gbogbo ti di ọ̀tun.
Gbogbo I.Y.P tó ń gba fúlàní gẹ́gẹ́bíi ẹ̀ṣọ́ aláabọ̀ tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ nínú ilé yín, tí ẹ fi ọmọ Yorùbá bíi tiyín sílẹ̀, ẹ̀ ń fi iná s’órí òrùlé sùn ni o.
Fúlàní kìí ṣe ọ̀rẹ́ ẹnikẹ́ni rárá, èròǹgbà wọn náà ni láti pa àti láti parun tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ tọ̀ọ́. Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a ṣọ́ra fún àlejò, kí a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa, ọ̀kan ni wá, kò sí ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa pé, lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.