Gẹ́gẹ́bí ohun tí Màmá wa ti máa nsọ, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, àrà ọ̀tọ̀ ni Ìṣèlú àti Ìṣèjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́.
Lọ́nà kíní, kò sí ọ̀rọ̀ owó gbígba ìwé tàbí fífi orúkọ sílẹ̀ láti díje fún ipò tí ó bá wu’ni.
Èyí jẹ́ pé ìrọ̀rùn ni ọ̀rọ̀ òṣèlú ní Democratic Republic of the Yoruba bá dé. Eléyí jẹ́ kí ó rọrùn fún ọ̀dọ́ láti kópa nínú ìdíje fún ipò nínú ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ kí ó rọrùn fún ẹni tí kò ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ owó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá tó máa jẹ́ tálákà, tí kò bá ti ṣe ọ̀lẹ.
Lọ́nà kéjì, Màmá sọ pé ẹni tó bá máa díje fún ipò níláti jẹ́ ẹni tí ó ngbé ní’lé, bó bá tilẹ̀ ngbé lẹ́yìn odi, yóò jẹ́ ẹni tó ń wá sí’lé lóòrè-kóòrè, àwọn èèyàn ibẹ̀ mọ̀-ọ́ gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe mọ onílé.
Ẹni ọ̀hún yóò jẹ́ ẹni tó mú ọ̀rọ̀ ilé ní ọ̀kúnkúndùn, tí ó mọ ilẹ̀, ó mọ àwọn èèyàn ibẹ̀, wọ́n ti mọ bó ṣe máa nwá’lé tí ó sì lọ́wọ́ nínú nkan tí wọ́n nṣe.
Bẹ́ẹ̀ ni ìdíje fún ipò òṣèlú kò gba kí a fún ‘ni lówó tàbí ohunkóhun míràn bí ẹni pé a ń ra ìbò lọ́wọ́ ara ìlú. Olùdíje á jáde láti sọ ti ẹnù rẹ̀ ni, kìí ṣe pé á fi ohunkóhun ra ẹ̀rí-ọkàn ará-ìlú.
Olùdíje fún ipò máa jẹ́ ẹni tí àwọn ará ìlú mọ̀ dáada, kìí ṣe ẹni tí ó jẹ́ pé torí pé ó fẹ́ gbé’gbá ìbò ló ṣe wá sí ìlú tàbí agbègbè nígbàtí àsìkò ìdìbò wọ’ lé dé.