Nínú ìrìn àjò wa sí òmìnira, ìgbésẹ ìgbàpadà tí a ṣe jẹ́ pàtàkì fún àwọn ìdí tí màmá wa, òrìṣà òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) ṣe àlàyé rẹ̀ fún wa nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi kí àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ní ìgbà àjọyọ̀ ọdún kejì Ifitónilétí gbígba ohun ìni wa padà ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Ọ̀pẹ ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún.

Ọ̀rọ̀ ìlanilọ́yẹ̀ màmá wa MOA jẹ́ ka mọ̀ pé ìdí tí àwa ọmọ I.Y.P fí ṣe ìfitónilétí ìgbàpadà ní pé, a kò sí ní ipò tí a wa tẹ́lẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ wa kí àwọn òyìnbó amúnisìn tó dé.

Nígbàtí àwọn amúnisìn dé, wọ́n bá wá ní orílẹ̀ èdè wa, nínú ìṣàkóso ara ẹni tí a ń ṣe rere, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ láti ma kó ohun àlùmọ́ọ́nì wa lọ sí ọ̀dọ̀ wọn.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n gba gbogbo ohun àlùmọ́ọ́nì naa, wọ́n wá gbé ìjọba wọn le wa lórí, wọ́n sì fi ètò àti ìlànà tiwọn ṣe pàṣípàrọ̀ fún wa, wọ́n gba èdè, àṣà àti ìṣe pẹ̀lú àwọn ohun ìdánimọ̀ wa míràn, tí wọ́n sì tún ń pè ilẹ̀ wa ní tiwọn torí wọ́n ti mú wa sìn bíi ẹrú.

Ètò ìmúnilẹ́rú yíì ló fàá tí a kò fi ní ẹnu ọ̀rọ̀ lórí ilẹ̀ wa mọ́, bíótilẹ̀jẹ́pẹ́ ibẹ̀ ní a wà, ṣùgbọ́n a wá dàbí àjòjì lórí ilẹ̀ àwọn babańlá wa. 

Màmá wa MOA tẹ̀síwájú pé, ní báyìí a wá ti padà sí ilẹ̀ wa, sí ipò wa, bí a ṣe wà tẹ́lẹ̀. A ti ní orílẹ̀ èdè wa, òmìnira wa, àti ìṣàkóso ara ẹni, kí àwọn òyìnbó amúnisìn tó dé. Ìdí rèé tí a níláti ṣe ìgbàpadà, Ọlọ́run ló bá wa rin ìrìn àjò náà tó sì bá wa ṣe ní àṣepé.

Ò fi rú àwọn ìkà agésùnmọ̀mí nàìjíríà lójú, odindi ọdún kan ni wọ́n fi kọ̀ láti gbé ìgbésẹ lórí ìwé ìfitónilétí ìgbàpadà tí a kọ sí wọ́n, nitori ìjọraẹni lójú àti ìgbéraga ọkàn wọn. 

Ọdún méjì tí pé lẹ́yìn ìfitónilétí ìgbàpadà wa. MOA, ìyá òmìnira wa sọ pé ìtúsílẹ̀ wa ti fìdímúlẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀,  gbogbo ìjẹgàba àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ni wọ́n máa fi ojú ba ilé ẹjọ́ àgbáyé láti jìyà ẹ̀sùn náà, bíi àwọn tó ṣe irú nkan bayìí ní àwọn orílẹ̀ èdè míràn ní àgbáyé, kò sí ọ̀nà àbáyọ, torí kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ̀.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal