Nínú ìròyìn tí a rí gbọ́, èyí tí ó pe àkíyèsí wa si, tí a wá ri pé orílẹ̀-èdè ibi tí ó ti ṣẹlẹ̀, jẹ́ èyí tí ọ̀rọ̀ ìṣerere ìlú wọn ká wọn lára.

Ilẹ̀ China ni ó ti ṣẹlẹ̀, a gbọ́ pé alága ilé-ìfowópamọ́ china tẹ́lẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Liu Liange, ni wọ́n ti ṣe ìdájọ́-ikú fún! Kíni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀? Wọ́n ní ó gba rìbá; ó sì tún ṣe ẹ̀yáwó fún àwọn ènìyàn lọ́nà tí ó lòdì sí òfin!

Nígbàtí wọ́n dá ẹjọ́-ikú yí fun ní ọjọ́ kẹ́rindínlọ́gbọ̀n, oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, wọ́n fun ní ànfààní ọdún-méjì, pé, láarín ọdún méjì yí, tí kò bá dá ọ̀ràn kankan, ó ṣeéṣe kí wọ́n yí ìdájọ́-ìkú náà sí ẹ̀wọ̀n-gbére!

Hmm. Ènìyàn, ẹ máa ṣọ́ra. Àt’ìdájọ́-ikú, àt’ẹ̀wọ̀n-gbére, kò sí èyí tí ó yẹ kí ọmọlúàbí ó rìn sí ibi tó ti máa ri he!

Ọmọ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á fi èyí ṣe àríkọ́gbọ́n o!

Lóotọ́, orílẹ̀-èdè tiwa ni Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ṣùgbọ́n a rí àpẹrẹ orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ pé wọn ò fẹ́ ohun tí ó máa ṣe àkóbá fún orílẹ̀-èdè wọn, àti fún ará-ìlú wọn!

Rìbá tí ọkùnrin náà gbà, lápapọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́tadínlógún owó dọ́là, nígbàtí ẹ̀yáwó tí ó ṣe fún àwọn èèyàn lọ́nà tí ó lòdì sí òfin, fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀tàlé-nírínwó ó lé márun, mílíọ̀nù dọ́là, èyí tí ó fa òfò àti àdánù tí ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rindínlọ́gbọ̀n dọ́là fún Orílẹ̀ èdè wọn.

Ohun tí ó ṣe pàtàkì, síwájú si, nínú ìdájọ́ yí ni pé, wọn ò ṣe ojúṣaájú kankan – wọn ò wo ti pé o ti jẹ́ ẹni pàtàkì ní ilú wọn tẹ́lẹ̀!

Yàtọ̀ sí pé wọ́n dá ẹjọ́ ikú fun, wọ́n tún gba gbogbo ohun-ìní tí ó ní, PÁTÁ, wọ́n sì tún sọ pé níwọ̀n ìgbà tó bá ṣì wà láyé o, kò ní ẹ̀tọ́ kankan lábẹ́ ìṣàkóso-ìlú wọn.

ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ (I.Y.P), ẹ jẹ́ kí á rántí, nígbàgbogbo pé tiwa yàtọ̀. – a kò gbọ́dọ̀ rí irúfẹ́ ìwà báyi, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).

Orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, kò sí fún ìwà-ìbàjẹ́ kankan. Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ni a máa tẹ̀lé, kò sì gbọdọ̀ sí ìwa-ìbàjẹ́ kankan ní orílẹ̀ èdè wa.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Tí ọmọdé bá ńjẹ èèwọ̀ tí ẹnìkan ò bi í, bó pẹ́ bó yá, ohun tí ńbi’ni ò ní ṣàì bi’ni.