ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Ààrẹ Ibrahim Traore ti ìlú Burkina Faso, ni a rí nínú fọ́nrán kan ní’bi tí ó ti ń bá àwọn olórí nínú ìjọba rẹ̀ sọ̀rọ̀; ó ní jagun-jagun ni òun o, òun kìí ṣe olóṣèlú; nítorí náà òun ò mọ bí wọ́n ṣe ń pẹ́ ẹnu sọ̀rọ̀; nítorí náà òótọ́ tààràtà ni òun ó sọ.

Ó ní ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn olùgbọ́ òun kó ní àànú àwọn ará-ìlú, látàrí  bí wọ́n ṣe wà nínú ìdẹ̀ra, ká jí láàárọ̀ ká kó sínú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ wa; a ń gbé ìgbé ayé tó dára, a ń jẹun tó dára lẹẹ̀mẹ́ta lójúmọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ; ó ní, ṣùgbọ́n àwọn olùgbọ́ òun kò ronú ti àwọn tí ó wà ní ìgbèríko, tí wọn ò rí ilé gbé torí àwọn agbésùnmọ̀mí kò jẹ́ kí wọn ó gbé ilé wọn; wọ́n ti di egungun tí a kàn fi awọ bò, látàrí ebi tí ó ń pa wọ́n. Koríko làwọn kan tilẹ̀ ń jẹ, nígbàtí kò sí oúnjẹ.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ó ní kí àwọn alábaṣiṣẹ́ òun ó la ojú wọn o, kí wọ́n máṣe rò pé yọ̀tọ̀mì tí àwọn wà yẹn ni ará-ìgbèríko Burkina Faso wà. Ó wá sọ àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n tí ń gbé, ṣùgbọ́n ó yẹ kí àwọn túbọ̀ ní àtìlẹyìn lát’ọ̀dọ̀ àwọn tó ní, láti túbọ̀ ran àwọn tí ìjọba ntọ́jú lọ́wọ́.

Ọ̀rọ̀ náà wú’ni lórí gidi, nítorí pé, ààrẹ Burkina Faso yí ní àfojúsùn rere fún àwọn tí wàhálà kò jẹ́ kí wọn ní ìbàlẹ̀-ọkàn. 

Ǹjẹ́ a le gbọ́ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yí, ká má rántí pé ìdẹ̀rùn fún ará-ìlú ló gbọ́dọ̀ jẹ́ àfojúsùn fún  ìjọba tí ó kún’jú ìwọ̀n fún orílẹ̀-èdè wọn?

A bá àwọn ará-ìlú Burkina yọ̀ a sì gba àdúrà pé kí ojú wọn ó rí ire tí Ààrẹ wọn ní lọ́kàn fún wọn.

Ọmọ Yorùbá, a kú orí-ire, pé a ní ìpìlẹ̀ tí ó kún’jú ìwọn, gẹ́gẹ́bí ògo adúláwọ̀! Ayọ̀ wa yí á túbọ̀ bí’mọ si lágbára Ẹlẹ́dàá wa. Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Màmá àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí Ìkẹ́ àti Ìgẹ̀ Olódùmarè kí ó máa wà láílaí pẹ̀lú yín.