Ohun t’ó dé, l’ó fa mo kó, mo rò!

Òwe Yorùbá

Agbésùnmọ̀mí Nigeria l’orí ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, ṣebí òun l’ó fa gbogbo àrí’fín àti ìwọ̀sí Nigeria tí ó nta bá wa, l’oní.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ṣùgbọ́n, ní àìpẹ́ àti ní àìjìnà, ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ti sọ wípé, gbogbo nkan burúkú tí a nrí l’orí ilẹ̀ wa báyi, a kò ní rí wọn mọ́!

L’orí ẹ̀rọ ayélujá’ra nínú ètò àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá náà ni a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìre’tí yí. Ọ̀rọ̀ náà wá rán wa l’etí wípé ní ọdún méjì s’ẹyìn ni ìkìlọ̀ ti dé wípé ohun tí ó máa ṣẹ’lẹ̀ ní ìlú ti a ti wá já’de kúrò nínú rẹ̀ báyí, ní ọdún 2023, kò níí ṣeé dúrò wò o!

Ka Ìròyìn: Pàtàkì Àgbékalẹ̀ (Blueprint) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y)

Ọ̀rọ̀ yí wá sí ìmúṣẹ o! Bákannáà, ní ọdún 2023 ni a tún gbọ́ wípé, màrìwò ni àwọn ènìyàn ṣì rí o! wípé eégún gan-an gan ṣì mbọ̀! Bẹ́ẹ̀ náà ni eléyí ti ṣẹ’lẹ̀ o!

A tún ti wá tún gbọ́ báyi o, wípé ohun tí ìlú tí a ti kúrò nínú rẹ̀ ti rí l’aárín ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí, títí di àkókò yí, kékeré l’ó ṣì jẹ́ o!

Ka Ìròyìn: Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà L’aárín June 12 Àti July 7

Àti wípé aburú t’ó jù bẹ́ẹ̀ lọ mbọ̀ ní ìyókù ọdún yí; àmọ́ ṣá o, ìròhìn ìrètí náà fi yé wa wípé, fún àwa ọmọ Yorùbá, ní orí ilẹ̀ Yorùbá, ìgbà díẹ̀ péré l’ó kù o! àwọn ibi àti ewu àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi ipá dúró s’orí ilẹ̀ wa yi, a kò níí rí wọn mọ́!

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá Ìròyìn